< Matteo 2 >

1 Or essendo Gesù nato in Betleem di Giudea, ai dì del re Erode, ecco dei magi d’Oriente arrivarono in Gerusalemme, dicendo:
Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu.
2 Dov’è il re de’ Giudei che è nato? Poiché noi abbiam veduto la sua stella in Oriente e siam venuti per adorarlo.
Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”
3 Udito questo, il re Erode fu turbato, e tutta Gerusalemme con lui.
Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀.
4 E radunati tutti i capi sacerdoti e gli scribi del popolo, s’informò da loro dove il Cristo dovea nascere.
Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi?
5 Ed essi gli dissero: In Betleem di Giudea; poiché così è scritto per mezzo del profeta:
Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé,
6 E tu, Betleem, terra di Giuda, non sei punto la minima fra le città principali di Giuda; perché da te uscirà un Principe, che pascerà il mio popolo Israele.
“‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea, ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’”
7 Allora Erode, chiamati di nascosto i magi, s’informò esattamente da loro del tempo in cui la stella era apparita;
Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.
8 e mandandoli a Betleem, disse loro: Andate e domandate diligentemente del fanciullino; e quando lo avrete trovato, fatemelo sapere, affinché io pure venga ad adorarlo.
Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”
9 Essi dunque, udito il re, partirono; ed ecco la stella che aveano veduta in Oriente, andava dinanzi a loro, finché, giunta al luogo dov’era il fanciullino, vi si fermò sopra.
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.
10 Ed essi, veduta la stella, si rallegrarono di grandissima allegrezza.
Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn.
11 Ed entrati nella casa, videro il fanciullino con Maria sua madre; e prostratisi, lo adorarono; ed aperti i loro tesori, gli offrirono dei doni: oro, incenso e mirra.
Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.
12 Poi, essendo stati divinamente avvertiti in sogno di non ripassare da Erode, per altra via tornarono al loro paese.
Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.
13 Partiti che furono, ecco un angelo del Signore apparve in sogno a Giuseppe e gli disse: Lèvati, prendi il fanciullino e sua madre, e fuggi in Egitto, e sta’ quivi finch’io non tel dica; perché Erode cercherà il fanciullino per farlo morire.
Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.”
14 Egli dunque, levatosi, prese di notte il fanciullino e sua madre, e si ritirò in Egitto;
Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti,
15 ed ivi stette fino alla morte di Erode, affinché si adempiesse quello che fu detto dal Signore per mezzo del profeta: Fuor d’Egitto chiamai il mio figliuolo.
ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”
16 Allora Erode, vedutosi beffato dai magi, si adirò gravemente, e mandò ad uccidere tutti i maschi ch’erano in Betleem e in tutto il suo territorio dall’età di due anni in giù, secondo il tempo del quale s’era esattamente informato dai magi.
Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.
17 Allora si adempié quello che fu detto per bocca del profeta Geremia:
Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé:
18 Un grido è stato udito in Rama; un pianto ed un lamento grande: Rachele piange i suoi figliuoli e ricusa d’esser consolata, perché non sono più.
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá, Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”
19 Ma dopo che Erode fu morto, ecco un angelo del Signore apparve in sogno a Giuseppe in Egitto, e gli disse:
Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti
20 Lèvati, prendi il fanciullino e sua madre, e vattene nel paese d’Israele; perché son morti coloro che cercavano la vita del fanciullino.
Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.”
21 Ed egli, levatosi, prese il fanciullino e sua madre ed entrò nel paese d’Israele.
Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli.
22 Ma udito che in Giudea regnava Archelao invece d’Erode, suo padre, temette d’andar colà; ed essendo stato divinamente avvertito in sogno, si ritirò nelle parti della Galilea,
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Akelausi ni ó ń jẹ ọba ní Judea ní ipò Herodu baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Galili lọ,
23 e venne ad abitare in una città detta Nazaret, affinché si adempiesse quello ch’era stato detto dai profeti, ch’egli sarebbe chiamato Nazareno.
ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Nasareti. Nígbà náà ni èyí tí a sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Nasareti.”

< Matteo 2 >