< Jób 24 >
1 Miért is nem titkolja el a Mindenható az ő büntetésének idejét, és miért is nem látják meg az őt ismerők az ő ítéletének napjait?!
“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́? Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
2 A határokat odább tolják, a nyájat elrabolják és legeltetik.
Wọ́n a sún àmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.
3 Az árvák szamarát elhajtják, és az özvegynek ökrét zálogba viszik.
Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
4 Lelökik az útról a szegényeket, és a föld nyomorultjai együtt lappanganak.
Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́.
5 Ímé, mint a vad szamarak a sivatagban, úgy mennek ki munkájukra élelmet keresni; a puszta ad nékik kenyeret fiaik számára.
Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
6 A mezőn a más vetését aratják, és a gonosznak szőlőjét szedik.
Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
7 Mezítelenül hálnak, testi ruha nélkül, még a hidegben sincs takarójuk.
Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
8 A hegyi zápor csurog le rólok, s hajlékuk nem lévén, a sziklát ölelik.
Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
9 Elszakítják az emlőtől az árvát, és a szegényen levőt zálogba viszik.
Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.
10 Mezítelenül járnak, ruha nélkül, és éhesen vonszolják a kévét.
Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà.
11 Az ő kerítéseik közt ütik az olajat, és tapossák a kádakat, de szomjuhoznak.
Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
12 A városból haldoklók rimánkodnak, a megsebzettek lelke kiált, de Isten nem törődik e méltatlansággal.
Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.
13 Ezek pártot ütöttek a világosság ellen, utait nem is ismerik, nem ülnek annak ösvényein.
“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14 Napkeltekor fölkel a gyilkos, megöli a szegényt és szűkölködőt, éjjel pedig olyan, mint a tolvaj.
Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.
15 A paráznának szeme pedig az alkonyatot lesi, mondván: Ne nézzen szem reám, és arczára álarczot teszen.
Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16 Setétben tör be a házakba; nappal elzárkóznak, nem szeretik a világosságot.
Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17 Sőt inkább a reggel nékik olyan, mint a halálnak árnyéka, mert megbarátkoztak a halál árnyékának félelmeivel.
Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
18 Könnyen siklik tova a víz színén, birtoka átkozott a földön, nem tér a szőlőkbe vivő útra.
“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19 Szárazság és hőség nyeli el a hó vizét, a pokol azokat, a kik vétkeznek. (Sheol )
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. (Sheol )
20 Elfelejti őt az anyaméh, féregnek lesz édességévé, nem emlékeznek róla többé, és összetörik, mint a reves fa,
Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀; a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi.
21 A ki megrontotta a meddőt, a ki nem szül, és az özvegygyel jót nem tett.
Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó.
22 De megtámogatja erejével a hatalmasokat; felkel az, pedig nem bízott már az élethez.
Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára, bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
23 Biztonságot ad néki, hogy támaszkodjék, de szemei vigyáznak azoknak útjaira.
Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un, àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24 Magasra emelkednek, egy kevés idő és már nincsenek! Alásülylyednek, mint akárki és elenyésznek; és levágattatnak, mint a búzakalász.
A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ; a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, a sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.
25 Avagy nem így van-é? Ki hazudtolhatna meg engem, és tehetné semmivé beszédemet?
“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”