< Jeremiás 19 >

1 Ezt mondja az Úr: Menj el és végy egy cserépkorsót a fazekastól, és némelyekkel a nép vénei közül és a papok vénei közül.
Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì.
2 Menj el a Ben-Hinnom völgyébe, a mely a fazekasok kapujának bejáratánál van, és kiáltsd ott azokat a szavakat, a melyeket én szólok néked;
Kí o sì lọ sí àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ.
3 És ezt mondjad: Halljátok meg az Úr szavát Júda királyai és Jeruzsálem lakosai: Ezt mondja a Seregek Ura, Izráel Istene: Ímé, én veszedelmet hozok e helyre, úgy hogy a ki csak hallja, megcsendül bele a füle.
Kí o sì wí pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya.
4 Azért, mert elhagytak engem, és idegenné tették e helyet, és idegen isteneknek áldoztak benne, a kiket sem ők nem ismertek, sem atyáik, sem Júda királyai, és eltöltötték e helyet ártatlan vérrel;
Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.
5 És magaslatokat építének a Baálnak, hogy megégessék fiaikat a tűzben, égőáldozatul a Baálnak, a mit én nem parancsoltam, sem nem rendeltem, és a mire nem is gondoltam.
Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi.
6 Azért ímé eljőnek a napok, azt mondja az Úr, és e hely nem neveztetik többé Tófetnek, sem Ben-Hinnom völgyének, hanem öldöklés völgyének.
Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.
7 És eszét vesztem e helyen Júdának és Jeruzsálemnek, és fegyverrel ejtem el őket ellenségeik előtt, és az életökre törőknek kezével; holttesteiket pedig az ég madarainak és a mezei vadaknak adom eledelül.
“‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.
8 És e várost csudává teszem és nevetséggé, a ki csak átmegy rajta, álmélkodik és szörnyűködik az ő nagy romlásán.
Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.
9 És megétetem velök az ő fiaik húsát és leányaik húsát és megeszi kiki az ő barátjának húsát, a megszállás alatt és a veszedelem alatt, a melylyel megszorongatják őket ellenségeik és a kik keresik az ő lelköket.
Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
10 Azután törd el e korsót azok szeme láttára, a kik elmennek veled.
“Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ.
11 És ezt mondd nékik: Ezt mondja a Seregek Ura: Így töröm össze e népet és e várost, a mint összetörhető e cserépedény, a mely többé meg sem építhető; és Tófetben temettetnek el, mert nem lesz más hely a temetkezésre.
Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́.
12 Így cselekszem e helylyel és ennek lakosaival, azt mondja az Úr, és olyanná teszem e várost, a milyen Tófet.
Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti.
13 És Jeruzsálem házai és Júda királyainak házai undokokká lesznek, mint a Tófet helye; mindazok a házak, a melyeknek tetején az ég egész seregének áldoztak és italáldozatot vittek az idegen isteneknek.
Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’”
14 Azután hazajöve Jeremiás Tófetből, a hová az Úr küldte vala őt prófétálni; megálla az Úr házának pitvarában, és szóla az egész népnek:
Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé,
15 Ezt mondja a Seregek Ura, Izráel Istene: Ímé én ráhozom e városra és ennek minden városára mindama veszedelmet, a melyről szóltam ő ellene; mert megkeményítették nyakukat, hogy ne hallják az én beszédeimet.
“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’”

< Jeremiás 19 >