< תהילים 91 >
ישב בסתר עליון בצל שדי יתלונן׃ | 1 |
Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
אמר ליהוה מחסי ומצודתי אלהי אבטח בו׃ | 2 |
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
כי הוא יצילך מפח יקוש מדבר הוות׃ | 3 |
Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
באברתו יסך לך ותחת כנפיו תחסה צנה וסחרה אמתו׃ | 4 |
Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
לא תירא מפחד לילה מחץ יעוף יומם׃ | 5 |
Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
מדבר באפל יהלך מקטב ישוד צהרים׃ | 6 |
tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
יפל מצדך אלף ורבבה מימינך אליך לא יגש׃ | 7 |
Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
רק בעיניך תביט ושלמת רשעים תראה׃ | 8 |
Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
כי אתה יהוה מחסי עליון שמת מעונך׃ | 9 |
Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
לא תאנה אליך רעה ונגע לא יקרב באהלך׃ | 10 |
Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́, Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
כי מלאכיו יצוה לך לשמרך בכל דרכיך׃ | 11 |
Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
על כפים ישאונך פן תגף באבן רגלך׃ | 12 |
wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
על שחל ופתן תדרך תרמס כפיר ותנין׃ | 13 |
Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀; ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
כי בי חשק ואפלטהו אשגבהו כי ידע שמי׃ | 14 |
“Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́; èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
יקראני ואענהו עמו אנכי בצרה אחלצהו ואכבדהו׃ | 15 |
Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.
ארך ימים אשביעהו ואראהו בישועתי׃ | 16 |
Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”