< תהילים 83 >
שיר מזמור לאסף אלהים אל דמי לך אל תחרש ואל תשקט אל׃ | 1 |
Orin. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
כי הנה אויביך יהמיון ומשנאיך נשאו ראש׃ | 2 |
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
על עמך יערימו סוד ויתיעצו על צפוניך׃ | 3 |
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
אמרו לכו ונכחידם מגוי ולא יזכר שם ישראל עוד׃ | 4 |
Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”
כי נועצו לב יחדו עליך ברית יכרתו׃ | 5 |
Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
אהלי אדום וישמעאלים מואב והגרים׃ | 6 |
Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli, ti Moabu àti ti Hagari
גבל ועמון ועמלק פלשת עם ישבי צור׃ | 7 |
Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
גם אשור נלוה עמם היו זרוע לבני לוט סלה׃ | 8 |
Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. (Sela)
עשה להם כמדין כסיסרא כיבין בנחל קישון׃ | 9 |
Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
נשמדו בעין דאר היו דמן לאדמה׃ | 10 |
ẹni tí ó ṣègbé ní Endori tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
שיתמו נדיבמו כערב וכזאב וכזבח וכצלמנע כל נסיכמו׃ | 11 |
Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu, àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
אשר אמרו נירשה לנו את נאות אלהים׃ | 12 |
tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”
אלהי שיתמו כגלגל כקש לפני רוח׃ | 13 |
Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
כאש תבער יער וכלהבה תלהט הרים׃ | 14 |
Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
כן תרדפם בסערך ובסופתך תבהלם׃ | 15 |
bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
מלא פניהם קלון ויבקשו שמך יהוה׃ | 16 |
Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.
יבשו ויבהלו עדי עד ויחפרו ויאבדו׃ | 17 |
Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
וידעו כי אתה שמך יהוה לבדך עליון על כל הארץ׃ | 18 |
jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa: pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.