< תהילים 73 >

מזמור לאסף אך טוב לישראל אלהים לברי לבב׃ 1
Saamu ti Asafu. Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
ואני כמעט נטוי רגלי כאין שפכה אשרי׃ 2
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
כי קנאתי בהוללים שלום רשעים אראה׃ 3
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
כי אין חרצבות למותם ובריא אולם׃ 4
Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.
בעמל אנוש אינמו ועם אדם לא ינגעו׃ 5
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
לכן ענקתמו גאוה יעטף שית חמס למו׃ 6
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
יצא מחלב עינמו עברו משכיות לבב׃ 7
Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.
ימיקו וידברו ברע עשק ממרום ידברו׃ 8
Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
שתו בשמים פיהם ולשונם תהלך בארץ׃ 9
Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé.
לכן ישיב עמו הלם ומי מלא ימצו למו׃ 10
Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
ואמרו איכה ידע אל ויש דעה בעליון׃ 11
Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
הנה אלה רשעים ושלוי עולם השגו חיל׃ 12
Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
אך ריק זכיתי לבבי וארחץ בנקיון כפי׃ 13
Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
ואהי נגוע כל היום ותוכחתי לבקרים׃ 14
Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
אם אמרתי אספרה כמו הנה דור בניך בגדתי׃ 15
Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
ואחשבה לדעת זאת עמל היא בעיני׃ 16
Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
עד אבוא אל מקדשי אל אבינה לאחריתם׃ 17
títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
אך בחלקות תשית למו הפלתם למשואות׃ 18
Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
איך היו לשמה כרגע ספו תמו מן בלהות׃ 19
Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
כחלום מהקיץ אדני בעיר צלמם תבזה׃ 20
Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
כי יתחמץ לבבי וכליותי אשתונן׃ 21
Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò,
ואני בער ולא אדע בהמות הייתי עמך׃ 22
mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.
ואני תמיד עמך אחזת ביד ימיני׃ 23
Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
בעצתך תנחני ואחר כבוד תקחני׃ 24
Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.
מי לי בשמים ועמך לא חפצתי בארץ׃ 25
Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
כלה שארי ולבבי צור לבבי וחלקי אלהים לעולם׃ 26
Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.
כי הנה רחקיך יאבדו הצמתה כל זונה ממך׃ 27
Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
ואני קרבת אלהים לי טוב שתי באדני יהוה מחסי לספר כל מלאכותיך׃ 28
Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run. Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi; kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

< תהילים 73 >