< תהילים 33 >

רננו צדיקים ביהוה לישרים נאוה תהלה׃ 1
Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
הודו ליהוה בכנור בנבל עשור זמרו לו׃ 2
Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
שירו לו שיר חדש היטיבו נגן בתרועה׃ 3
Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
כי ישר דבר יהוה וכל מעשהו באמונה׃ 4
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
אהב צדקה ומשפט חסד יהוה מלאה הארץ׃ 5
Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.
בדבר יהוה שמים נעשו וברוח פיו כל צבאם׃ 6
Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
כנס כנד מי הים נתן באצרות תהומות׃ 7
Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
ייראו מיהוה כל הארץ ממנו יגורו כל ישבי תבל׃ 8
Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
כי הוא אמר ויהי הוא צוה ויעמד׃ 9
Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.
יהוה הפיר עצת גוים הניא מחשבות עמים׃ 10
Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
עצת יהוה לעולם תעמד מחשבות לבו לדר ודר׃ 11
Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
אשרי הגוי אשר יהוה אלהיו העם בחר לנחלה לו׃ 12
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
משמים הביט יהוה ראה את כל בני האדם׃ 13
Olúwa wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
ממכון שבתו השגיח אל כל ישבי הארץ׃ 14
Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
היצר יחד לבם המבין אל כל מעשיהם׃ 15
ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
אין המלך נושע ברב חיל גבור לא ינצל ברב כח׃ 16
A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
שקר הסוס לתשועה וברב חילו לא ימלט׃ 17
Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
הנה עין יהוה אל יראיו למיחלים לחסדו׃ 18
Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
להציל ממות נפשם ולחיותם ברעב׃ 19
Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
נפשנו חכתה ליהוה עזרנו ומגננו הוא׃ 20
Ọkàn wa dúró de Olúwa; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
כי בו ישמח לבנו כי בשם קדשו בטחנו׃ 21
Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
יהי חסדך יהוה עלינו כאשר יחלנו לך׃ 22
Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

< תהילים 33 >