< תהילים 15 >

מזמור לדוד יהוה מי יגור באהלך מי ישכן בהר קדשך׃ 1
Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
הולך תמים ופעל צדק ודבר אמת בלבבו׃ 2
Ẹni tí ń rìn déédé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn rẹ̀;
לא רגל על לשנו לא עשה לרעהו רעה וחרפה לא נשא על קרבו׃ 3
tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
נבזה בעיניו נמאס ואת יראי יהוה יכבד נשבע להרע ולא ימר׃ 4
ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀ àní tí kò sì yípadà,
כספו לא נתן בנשך ושחד על נקי לא לקח עשה אלה לא ימוט לעולם׃ 5
tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé.

< תהילים 15 >