< תהילים 139 >

למנצח לדוד מזמור יהוה חקרתני ותדע׃ 1
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.
אתה ידעת שבתי וקומי בנתה לרעי מרחוק׃ 2
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
ארחי ורבעי זרית וכל דרכי הסכנתה׃ 3
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
כי אין מלה בלשוני הן יהוה ידעת כלה׃ 4
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
אחור וקדם צרתני ותשת עלי כפכה׃ 5
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
פלאיה דעת ממני נשגבה לא אוכל לה׃ 6
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
אנה אלך מרוחך ואנה מפניך אברח׃ 7
Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
אם אסק שמים שם אתה ואציעה שאול הנך׃ (Sheol h7585) 8
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Sheol h7585)
אשא כנפי שחר אשכנה באחרית ים׃ 9
Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,
גם שם ידך תנחני ותאחזני ימינך׃ 10
àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
ואמר אך חשך ישופני ולילה אור בעדני׃ 11
Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
גם חשך לא יחשיך ממך ולילה כיום יאיר כחשיכה כאורה׃ 12
Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
כי אתה קנית כליתי תסכני בבטן אמי׃ 13
Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
אודך על כי נוראות נפליתי נפלאים מעשיך ונפשי ידעת מאד׃ 14
Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.
לא נכחד עצמי ממך אשר עשיתי בסתר רקמתי בתחתיות ארץ׃ 15
Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
גלמי ראו עיניך ועל ספרך כלם יכתבו ימים יצרו ולא אחד בהם׃ 16
ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé, àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
ולי מה יקרו רעיך אל מה עצמו ראשיהם׃ 17
Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!
אספרם מחול ירבון הקיצתי ועודי עמך׃ 18
Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye: nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
אם תקטל אלוה רשע ואנשי דמים סורו מני׃ 19
Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
אשר יאמרך למזמה נשא לשוא עריך׃ 20
Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
הלוא משנאיך יהוה אשנא ובתקוממיך אתקוטט׃ 21
Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
תכלית שנאה שנאתים לאויבים היו לי׃ 22
Èmi kórìíra wọn ní àkótán; èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
חקרני אל ודע לבבי בחנני ודע שרעפי׃ 23
Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.
וראה אם דרך עצב בי ונחני בדרך עולם׃ 24
Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

< תהילים 139 >