< תהילים 135 >

הללו יה הללו את שם יהוה הללו עבדי יהוה׃ 1
Ẹ yin Olúwa. Ẹ yin orúkọ Olúwa; ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
שעמדים בבית יהוה בחצרות בית אלהינו׃ 2
Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
הללו יה כי טוב יהוה זמרו לשמו כי נעים׃ 3
Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
כי יעקב בחר לו יה ישראל לסגלתו׃ 4
Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀; àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
כי אני ידעתי כי גדול יהוה ואדנינו מכל אלהים׃ 5
Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
כל אשר חפץ יהוה עשה בשמים ובארץ בימים וכל תהומות׃ 6
Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
מעלה נשאים מקצה הארץ ברקים למטר עשה מוצא רוח מאוצרותיו׃ 7
Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
שהכה בכורי מצרים מאדם עד בהמה׃ 8
Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti, àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
שלח אתות ומפתים בתוככי מצרים בפרעה ובכל עבדיו׃ 9
Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
שהכה גוים רבים והרג מלכים עצומים׃ 10
Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
לסיחון מלך האמרי ולעוג מלך הבשן ולכל ממלכות כנען׃ 11
Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
ונתן ארצם נחלה נחלה לישראל עמו׃ 12
Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
יהוה שמך לעולם יהוה זכרך לדר ודר׃ 13
Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
כי ידין יהוה עמו ועל עבדיו יתנחם׃ 14
Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
עצבי הגוים כסף וזהב מעשה ידי אדם׃ 15
Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
פה להם ולא ידברו עינים להם ולא יראו׃ 16
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
אזנים להם ולא יאזינו אף אין יש רוח בפיהם׃ 17
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn.
כמוהם יהיו עשיהם כל אשר בטח בהם׃ 18
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
בית ישראל ברכו את יהוה בית אהרן ברכו את יהוה׃ 19
Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
בית הלוי ברכו את יהוה יראי יהוה ברכו את יהוה׃ 20
Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
ברוך יהוה מציון שכן ירושלם הללו יה׃ 21
Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá, tí ń gbé Jerusalẹmu. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

< תהילים 135 >