< תהילים 118 >

הודו ליהוה כי טוב כי לעולם חסדו׃ 1
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ dúró láéláé.
יאמר נא ישראל כי לעולם חסדו׃ 2
Jẹ́ kí Israẹli wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
יאמרו נא בית אהרן כי לעולם חסדו׃ 3
Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
יאמרו נא יראי יהוה כי לעולם חסדו׃ 4
Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
מן המצר קראתי יה ענני במרחב יה׃ 5
Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa, ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
יהוה לי לא אירא מה יעשה לי אדם׃ 6
Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
יהוה לי בעזרי ואני אראה בשנאי׃ 7
Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi. Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
טוב לחסות ביהוה מבטח באדם׃ 8
Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
טוב לחסות ביהוה מבטח בנדיבים׃ 9
Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
כל גוים סבבוני בשם יהוה כי אמילם׃ 10
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò.
סבוני גם סבבוני בשם יהוה כי אמילם׃ 11
Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù.
סבוני כדבורים דעכו כאש קוצים בשם יהוה כי אמילם׃ 12
Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin, ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún; ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
דחה דחיתני לנפל ויהוה עזרני׃ 13
Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú, ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
עזי וזמרת יה ויהי לי לישועה׃ 14
Olúwa ni agbára àti orin mi; ó sì di ìgbàlà mi.
קול רנה וישועה באהלי צדיקים ימין יהוה עשה חיל׃ 15
Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo: “Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
ימין יהוה רוממה ימין יהוה עשה חיל׃ 16
Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga; ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
לא אמות כי אחיה ואספר מעשי יה׃ 17
Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
יסר יסרני יה ולמות לא נתנני׃ 18
Olúwa bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
פתחו לי שערי צדק אבא בם אודה יה׃ 19
Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi: èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
זה השער ליהוה צדיקים יבאו בו׃ 20
Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
אודך כי עניתני ותהי לי לישועה׃ 21
Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn; ìwọ sì di ìgbàlà mi.
אבן מאסו הבונים היתה לראש פנה׃ 22
Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé;
מאת יהוה היתה זאת היא נפלאת בעינינו׃ 23
Olúwa ti ṣe èyí, ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
זה היום עשה יהוה נגילה ונשמחה בו׃ 24
Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
אנא יהוה הושיעה נא אנא יהוה הצליחה נא׃ 25
Olúwa, gbà wá; Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
ברוך הבא בשם יהוה ברכנוכם מבית יהוה׃ 26
Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa. Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
אל יהוה ויאר לנו אסרו חג בעבתים עד קרנות המזבח׃ 27
Olúwa ni Ọlọ́run, ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
אלי אתה ואודך אלהי ארוממך׃ 28
Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ; ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
הודו ליהוה כי טוב כי לעולם חסדו׃ 29
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

< תהילים 118 >