< תהילים 115 >

לא לנו יהוה לא לנו כי לשמך תן כבוד על חסדך על אמתך׃ 1
Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ.
למה יאמרו הגוים איה נא אלהיהם׃ 2
Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà.
ואלהינו בשמים כל אשר חפץ עשה׃ 3
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
עצביהם כסף וזהב מעשה ידי אדם׃ 4
Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
פה להם ולא ידברו עינים להם ולא יראו׃ 5
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
אזנים להם ולא ישמעו אף להם ולא יריחון׃ 6
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn.
ידיהם ולא ימישון רגליהם ולא יהלכו לא יהגו בגרונם׃ 7
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
כמוהם יהיו עשיהם כל אשר בטח בהם׃ 8
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
ישראל בטח ביהוה עזרם ומגנם הוא׃ 9
Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
בית אהרן בטחו ביהוה עזרם ומגנם הוא׃ 10
Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
יראי יהוה בטחו ביהוה עזרם ומגנם הוא׃ 11
Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
יהוה זכרנו יברך יברך את בית ישראל יברך את בית אהרן׃ 12
Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli; yóò bùkún ilé Aaroni.
יברך יראי יהוה הקטנים עם הגדלים׃ 13
Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, àti kékeré àti ńlá.
יסף יהוה עליכם עליכם ועל בניכם׃ 14
Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
ברוכים אתם ליהוה עשה שמים וארץ׃ 15
Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
השמים שמים ליהוה והארץ נתן לבני אדם׃ 16
Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa: ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
לא המתים יהללו יה ולא כל ירדי דומה׃ 17
Òkú kò lè yìn Olúwa, tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
ואנחנו נברך יה מעתה ועד עולם הללו יה׃ 18
Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ẹ yin Olúwa.

< תהילים 115 >