< תהילים 103 >

לדוד ברכי נפשי את יהוה וכל קרבי את שם קדשו׃ 1
Ti Dafidi. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
ברכי נפשי את יהוה ואל תשכחי כל גמוליו׃ 2
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,
הסלח לכל עונכי הרפא לכל תחלאיכי׃ 3
ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
הגואל משחת חייכי המעטרכי חסד ורחמים׃ 4
ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
המשביע בטוב עדיך תתחדש כנשר נעוריכי׃ 5
ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
עשה צדקות יהוה ומשפטים לכל עשוקים׃ 6
Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ni lára.
יודיע דרכיו למשה לבני ישראל עלילותיו׃ 7
Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
רחום וחנון יהוה ארך אפים ורב חסד׃ 8
Olúwa ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
לא לנצח יריב ולא לעולם יטור׃ 9
Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,
לא כחטאינו עשה לנו ולא כעונתינו גמל עלינו׃ 10
Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa.
כי כגבה שמים על הארץ גבר חסדו על יראיו׃ 11
Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
כרחק מזרח ממערב הרחיק ממנו את פשעינו׃ 12
Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
כרחם אב על בנים רחם יהוה על יראיו׃ 13
Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
כי הוא ידע יצרנו זכור כי עפר אנחנו׃ 14
nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
אנוש כחציר ימיו כציץ השדה כן יציץ׃ 15
Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó,
כי רוח עברה בו ואיננו ולא יכירנו עוד מקומו׃ 16
afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
וחסד יהוה מעולם ועד עולם על יראיו וצדקתו לבני בנים׃ 17
Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,
לשמרי בריתו ולזכרי פקדיו לעשותם׃ 18
sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
יהוה בשמים הכין כסאו ומלכותו בכל משלה׃ 19
Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
ברכו יהוה מלאכיו גברי כח עשי דברו לשמע בקול דברו׃ 20
Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.
ברכו יהוה כל צבאיו משרתיו עשי רצונו׃ 21
Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
ברכו יהוה כל מעשיו בכל מקמות ממשלתו ברכי נפשי את יהוה׃ 22
Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ibi gbogbo ìjọba rẹ̀. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

< תהילים 103 >