< מִשְׁלֵי 4 >
שמעו בנים מוסר אב והקשיבו לדעת בינה׃ | 1 |
Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
כי לקח טוב נתתי לכם תורתי אל תעזבו׃ | 2 |
Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.
כי בן הייתי לאבי רך ויחיד לפני אמי׃ | 3 |
Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.
וירני ויאמר לי יתמך דברי לבך שמר מצותי וחיה׃ | 4 |
Ó kọ́ mi ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
קנה חכמה קנה בינה אל תשכח ואל תט מאמרי פי׃ | 5 |
Gba ọgbọ́n, gba òye, má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.
אל תעזבה ותשמרך אהבה ותצרך׃ | 6 |
Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
ראשית חכמה קנה חכמה ובכל קנינך קנה בינה׃ | 7 |
Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.
סלסלה ותרוממך תכבדך כי תחבקנה׃ | 8 |
Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
תתן לראשך לוית חן עטרת תפארת תמגנך׃ | 9 |
Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
שמע בני וקח אמרי וירבו לך שנות חיים׃ | 10 |
Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
בדרך חכמה הרתיך הדרכתיך במעגלי ישר׃ | 11 |
Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
בלכתך לא יצר צעדך ואם תרוץ לא תכשל׃ | 12 |
Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
החזק במוסר אל תרף נצרה כי היא חייך׃ | 13 |
Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
בארח רשעים אל תבא ואל תאשר בדרך רעים׃ | 14 |
Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
פרעהו אל תעבר בו שטה מעליו ועבור׃ | 15 |
Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.
כי לא ישנו אם לא ירעו ונגזלה שנתם אם לא יכשולו׃ | 16 |
Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.
כי לחמו לחם רשע ויין חמסים ישתו׃ | 17 |
Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
וארח צדיקים כאור נגה הולך ואור עד נכון היום׃ | 18 |
Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
דרך רשעים כאפלה לא ידעו במה יכשלו׃ | 19 |
ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
בני לדברי הקשיבה לאמרי הט אזנך׃ | 20 |
Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.
אל יליזו מעיניך שמרם בתוך לבבך׃ | 21 |
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,
כי חיים הם למצאיהם ולכל בשרו מרפא׃ | 22 |
nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.
מכל משמר נצר לבך כי ממנו תוצאות חיים׃ | 23 |
Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè.
הסר ממך עקשות פה ולזות שפתים הרחק ממך׃ | 24 |
Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
עיניך לנכח יביטו ועפעפיך יישרו נגדך׃ | 25 |
Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
פלס מעגל רגלך וכל דרכיך יכנו׃ | 26 |
Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
אל תט ימין ושמאול הסר רגלך מרע׃ | 27 |
Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.