< מִשְׁלֵי 28 >

נסו ואין רדף רשע וצדיקים ככפיר יבטח׃ 1
Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
בפשע ארץ רבים שריה ובאדם מבין ידע כן יאריך׃ 2
Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀, ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.
גבר רש ועשק דלים מטר סחף ואין לחם׃ 3
Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.
עזבי תורה יהללו רשע ושמרי תורה יתגרו בם׃ 4
Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
אנשי רע לא יבינו משפט ומבקשי יהוה יבינו כל׃ 5
Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.
טוב רש הולך בתמו מעקש דרכים והוא עשיר׃ 6
Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
נוצר תורה בן מבין ורעה זוללים יכלים אביו׃ 7
Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.
מרבה הונו בנשך ובתרבית לחונן דלים יקבצנו׃ 8
Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
מסיר אזנו משמע תורה גם תפלתו תועבה׃ 9
Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
משגה ישרים בדרך רע בשחותו הוא יפול ותמימים ינחלו טוב׃ 10
Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
חכם בעיניו איש עשיר ודל מבין יחקרנו׃ 11
Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
בעלץ צדיקים רבה תפארת ובקום רשעים יחפש אדם׃ 12
Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
מכסה פשעיו לא יצליח ומודה ועזב ירחם׃ 13
Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
אשרי אדם מפחד תמיד ומקשה לבו יפול ברעה׃ 14
Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
ארי נהם ודב שוקק משל רשע על עם דל׃ 15
Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
נגיד חסר תבונות ורב מעשקות שנאי בצע יאריך ימים׃ 16
Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.
אדם עשק בדם נפש עד בור ינוס אל יתמכו בו׃ 17
Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
הולך תמים יושע ונעקש דרכים יפול באחת׃ 18
Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.
עבד אדמתו ישבע לחם ומרדף רקים ישבע ריש׃ 19
Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
איש אמונות רב ברכות ואץ להעשיר לא ינקה׃ 20
Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.
הכר פנים לא טוב ועל פת לחם יפשע גבר׃ 21
Ojúsàájú ṣíṣe kò dára, síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
נבהל להון איש רע עין ולא ידע כי חסר יבאנו׃ 22
Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
מוכיח אדם אחרי חן ימצא ממחליק לשון׃ 23
Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
גוזל אביו ואמו ואמר אין פשע חבר הוא לאיש משחית׃ 24
Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
רחב נפש יגרה מדון ובוטח על יהוה ידשן׃ 25
Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.
בוטח בלבו הוא כסיל והולך בחכמה הוא ימלט׃ 26
Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
נותן לרש אין מחסור ומעלים עיניו רב מארות׃ 27
Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
בקום רשעים יסתר אדם ובאבדם ירבו צדיקים׃ 28
Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.

< מִשְׁלֵי 28 >