< מִשְׁלֵי 25 >
גם אלה משלי שלמה אשר העתיקו אנשי חזקיה מלך יהודה׃ | 1 |
Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.
כבד אלהים הסתר דבר וכבד מלכים חקר דבר׃ | 2 |
Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
שמים לרום וארץ לעמק ולב מלכים אין חקר׃ | 3 |
Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.
הגו סיגים מכסף ויצא לצרף כלי׃ | 4 |
Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.
הגו רשע לפני מלך ויכון בצדק כסאו׃ | 5 |
Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.
אל תתהדר לפני מלך ובמקום גדלים אל תעמד׃ | 6 |
Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,
כי טוב אמר לך עלה הנה מהשפילך לפני נדיב אשר ראו עיניך׃ | 7 |
ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,” ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.
אל תצא לרב מהר פן מה תעשה באחריתה בהכלים אתך רעך׃ | 8 |
Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?
ריבך ריב את רעך וסוד אחר אל תגל׃ | 9 |
Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
פן יחסדך שמע ודבתך לא תשוב׃ | 10 |
àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.
תפוחי זהב במשכיות כסף דבר דבר על אפניו׃ | 11 |
Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
נזם זהב וחלי כתם מוכיח חכם על אזן שמעת׃ | 12 |
Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.
כצנת שלג ביום קציר ציר נאמן לשלחיו ונפש אדניו ישיב׃ | 13 |
Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
נשיאים ורוח וגשם אין איש מתהלל במתת שקר׃ | 14 |
Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.
בארך אפים יפתה קצין ולשון רכה תשבר גרם׃ | 15 |
Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
דבש מצאת אכל דיך פן תשבענו והקאתו׃ | 16 |
Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
הקר רגלך מבית רעך פן ישבעך ושנאך׃ | 17 |
Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.
מפיץ וחרב וחץ שנון איש ענה ברעהו עד שקר׃ | 18 |
Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.
שן רעה ורגל מועדת מבטח בוגד ביום צרה׃ | 19 |
Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
מעדה בגד ביום קרה חמץ על נתר ושר בשרים על לב רע׃ | 20 |
Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́, ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.
אם רעב שנאך האכלהו לחם ואם צמא השקהו מים׃ | 21 |
Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
כי גחלים אתה חתה על ראשו ויהוה ישלם לך׃ | 22 |
Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
רוח צפון תחולל גשם ופנים נזעמים לשון סתר׃ | 23 |
Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
טוב שבת על פנת גג מאשת מדונים ובית חבר׃ | 24 |
Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.
מים קרים על נפש עיפה ושמועה טובה מארץ מרחק׃ | 25 |
Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.
מעין נרפש ומקור משחת צדיק מט לפני רשע׃ | 26 |
Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.
אכל דבש הרבות לא טוב וחקר כבדם כבוד׃ | 27 |
Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.
עיר פרוצה אין חומה איש אשר אין מעצר לרוחו׃ | 28 |
Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.