< מִשְׁלֵי 19 >

טוב רש הולך בתמו מעקש שפתיו והוא כסיל׃ 1
Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
גם בלא דעת נפש לא טוב ואץ ברגלים חוטא׃ 2
Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
אולת אדם תסלף דרכו ועל יהוה יזעף לבו׃ 3
Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.
הון יסיף רעים רבים ודל מרעהו יפרד׃ 4
Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
עד שקרים לא ינקה ויפיח כזבים לא ימלט׃ 5
Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
רבים יחלו פני נדיב וכל הרע לאיש מתן׃ 6
Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
כל אחי רש שנאהו אף כי מרעהו רחקו ממנו מרדף אמרים לא המה׃ 7
Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì, mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
קנה לב אהב נפשו שמר תבונה למצא טוב׃ 8
Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
עד שקרים לא ינקה ויפיח כזבים יאבד׃ 9
Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
לא נאוה לכסיל תענוג אף כי לעבד משל בשרים׃ 10
Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
שכל אדם האריך אפו ותפארתו עבר על פשע׃ 11
Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
נהם ככפיר זעף מלך וכטל על עשב רצונו׃ 12
Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
הות לאביו בן כסיל ודלף טרד מדיני אשה׃ 13
Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
בית והון נחלת אבות ומיהוה אשה משכלת׃ 14
A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí, ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
עצלה תפיל תרדמה ונפש רמיה תרעב׃ 15
Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn, ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
שמר מצוה שמר נפשו בוזה דרכיו יומת׃ 16
Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
מלוה יהוה חונן דל וגמלו ישלם לו׃ 17
Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá, yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
יסר בנך כי יש תקוה ואל המיתו אל תשא נפשך׃ 18
Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.
גרל חמה נשא ענש כי אם תציל ועוד תוסף׃ 19
Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀; bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
שמע עצה וקבל מוסר למען תחכם באחריתך׃ 20
Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
רבות מחשבות בלב איש ועצת יהוה היא תקום׃ 21
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.
תאות אדם חסדו וטוב רש מאיש כזב׃ 22
Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
יראת יהוה לחיים ושבע ילין בל יפקד רע׃ 23
Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá; nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.
טמן עצל ידו בצלחת גם אל פיהו לא ישיבנה׃ 24
Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ; kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
לץ תכה ופתי יערם והוכיח לנבון יבין דעת׃ 25
Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.
משדד אב יבריח אם בן מביש ומחפיר׃ 26
Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.
חדל בני לשמע מוסר לשגות מאמרי דעת׃ 27
Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́, tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
עד בליעל יליץ משפט ופי רשעים יבלע און׃ 28
Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín, ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.
נכונו ללצים שפטים ומהלמות לגו כסילים׃ 29
A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.

< מִשְׁלֵי 19 >