< במדבר 33 >

אלה מסעי בני ישראל אשר יצאו מארץ מצרים לצבאתם ביד משה ואהרן׃ 1
Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
ויכתב משה את מוצאיהם למסעיהם על פי יהוה ואלה מסעיהם למוצאיהם׃ 2
Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa, wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.
ויסעו מרעמסס בחדש הראשון בחמשה עשר יום לחדש הראשון ממחרת הפסח יצאו בני ישראל ביד רמה לעיני כל מצרים׃ 3
Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.
ומצרים מקברים את אשר הכה יהוה בהם כל בכור ובאלהיהם עשה יהוה שפטים׃ 4
Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.
ויסעו בני ישראל מרעמסס ויחנו בסכת׃ 5
Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti.
ויסעו מסכת ויחנו באתם אשר בקצה המדבר׃ 6
Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù.
ויסעו מאתם וישב על פי החירת אשר על פני בעל צפון ויחנו לפני מגדל׃ 7
Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.
ויסעו מפני החירת ויעברו בתוך הים המדברה וילכו דרך שלשת ימים במדבר אתם ויחנו במרה׃ 8
Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín òkun kọjá lọ sí aginjù. Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara.
ויסעו ממרה ויבאו אילמה ובאילם שתים עשרה עינת מים ושבעים תמרים ויחנו שם׃ 9
Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.
ויסעו מאילם ויחנו על ים סוף׃ 10
Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.
ויסעו מים סוף ויחנו במדבר סין׃ 11
Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini.
ויסעו ממדבר סין ויחנו בדפקה׃ 12
Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka.
ויסעו מדפקה ויחנו באלוש׃ 13
Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi.
ויסעו מאלוש ויחנו ברפידם ולא היה שם מים לעם לשתות׃ 14
Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.
ויסעו מרפידם ויחנו במדבר סיני׃ 15
Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai.
ויסעו ממדבר סיני ויחנו בקברת התאוה׃ 16
Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa.
ויסעו מקברת התאוה ויחנו בחצרת׃ 17
Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu.
ויסעו מחצרת ויחנו ברתמה׃ 18
Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma.
ויסעו מרתמה ויחנו ברמן פרץ׃ 19
Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi.
ויסעו מרמן פרץ ויחנו בלבנה׃ 20
Wọ́n kúrò ní Rimoni-Peresi wọ́n sì pàgọ́ ní Libina.
ויסעו מלבנה ויחנו ברסה׃ 21
Wọ́n kúrò ní Libina wọ́n sì pàgọ́ ní Rissa.
ויסעו מרסה ויחנו בקהלתה׃ 22
Wọ́n kúrò ní Rissa wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelata.
ויסעו מקהלתה ויחנו בהר שפר׃ 23
Wọ́n kúrò ní Kehelata wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣeferi.
ויסעו מהר שפר ויחנו בחרדה׃ 24
Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣeferi wọ́n sì pàgọ́ ní Harada.
ויסעו מחרדה ויחנו במקהלת׃ 25
Wọ́n kúrò ní Harada wọ́n sì pàgọ́ ní Makhelotu.
ויסעו ממקהלת ויחנו בתחת׃ 26
Wọ́n kúrò ní Makhelotu wọ́n sì pàgọ́ ní Tahati.
ויסעו מתחת ויחנו בתרח׃ 27
Wọ́n kúrò ní Tahati wọ́n sì pàgọ́ ní Tẹra.
ויסעו מתרח ויחנו במתקה׃ 28
Wọ́n kúrò ní Tẹra wọ́n sì pàgọ́ ní Mitka.
ויסעו ממתקה ויחנו בחשמנה׃ 29
Wọ́n kúrò ní Mitka wọ́n pàgọ́ ní Haṣmona.
ויסעו מחשמנה ויחנו במסרות׃ 30
Wọ́n kúrò ní Haṣmona wọ́n sì pàgọ́ ní Moserotu.
ויסעו ממסרות ויחנו בבני יעקן׃ 31
Wọ́n kúrò ní Moserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jaakani.
ויסעו מבני יעקן ויחנו בחר הגדגד׃ 32
Wọ́n kúrò ní Bene-Jaakani wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Haggidgadi.
ויסעו מחר הגדגד ויחנו ביטבתה׃ 33
Wọ́n kúrò ní Hori-Haggidgadi wọ́n sí pàgọ́ ní Jotbata.
ויסעו מיטבתה ויחנו בעברנה׃ 34
Wọ́n kúrò ní Jotbata wọ́n sì pàgọ́ ní Abrona.
ויסעו מעברנה ויחנו בעציון גבר׃ 35
Wọ́n kúrò ní Abrona wọ́n sì pàgọ́ ní Esioni-Geberi.
ויסעו מעציון גבר ויחנו במדבר צן הוא קדש׃ 36
Wọ́n kúrò ní Esioni-Geberi wọ́n sì pàgọ́ ní Kadeṣi nínú aginjù Sini.
ויסעו מקדש ויחנו בהר ההר בקצה ארץ אדום׃ 37
Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu.
ויעל אהרן הכהן אל הר ההר על פי יהוה וימת שם בשנת הארבעים לצאת בני ישראל מארץ מצרים בחדש החמישי באחד לחדש׃ 38
Nípa àṣẹ Olúwa, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá.
ואהרן בן שלש ועשרים ומאת שנה במתו בהר ההר׃ 39
Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori.
וישמע הכנעני מלך ערד והוא ישב בנגב בארץ כנען בבא בני ישראל׃ 40
Àwọn ará Kenaani, ọba Aradi, tí ń gbé ìhà gúúsù ní ilẹ̀ Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.
ויסעו מהר ההר ויחנו בצלמנה׃ 41
Wọ́n kúrò ní orí òkè Hori, wọ́n sì pàgọ́ ní Salmona.
ויסעו מצלמנה ויחנו בפונן׃ 42
Wọ́n kúrò ní Salmona wọ́n sì pàgọ́ ní Punoni.
ויסעו מפונן ויחנו באבת׃ 43
Wọ́n kúrò ní Punoni wọ́n sì pàgọ́ ní Obotu.
ויסעו מאבת ויחנו בעיי העברים בגבול מואב׃ 44
Wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Abarimu, ní agbègbè Moabu.
ויסעו מעיים ויחנו בדיבן גד׃ 45
Wọ́n kúrò ní Iyimu, wọ́n sì pàgọ́ ní Diboni-Gadi.
ויסעו מדיבן גד ויחנו בעלמן דבלתימה׃ 46
Wọ́n kúrò ní Diboni-Gadi wọ́n sì pàgọ́ ní Alimon-Diblataimu.
ויסעו מעלמן דבלתימה ויחנו בהרי העברים לפני נבו׃ 47
Wọ́n kúrò ní Alimon-Diblataimu wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Abarimu lẹ́bàá Nebo.
ויסעו מהרי העברים ויחנו בערבת מואב על ירדן ירחו׃ 48
Wọ́n kúrò ní orí òkè Abarimu wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani ní ìkọjá Jeriko.
ויחנו על הירדן מבית הישמת עד אבל השטים בערבת מואב׃ 49
Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jordani láti Beti-Jeṣimoti títí dé Abeli-Ṣittimu.
וידבר יהוה אל משה בערבת מואב על ירדן ירחו לאמר׃ 50
Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá Jordani, létí Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé,
דבר אל בני ישראל ואמרת אלהם כי אתם עברים את הירדן אל ארץ כנען׃ 51
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jordani lọ sí Kenaani,
והורשתם את כל ישבי הארץ מפניכם ואבדתם את כל משכיתם ואת כל צלמי מסכתם תאבדו ואת כל במתם תשמידו׃ 52
lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀.
והורשתם את הארץ וישבתם בה כי לכם נתתי את הארץ לרשת אתה׃ 53
Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín.
והתנחלתם את הארץ בגורל למשפחתיכם לרב תרבו את נחלתו ולמעט תמעיט את נחלתו אל אשר יצא לו שמה הגורל לו יהיה למטות אבתיכם תתנחלו׃ 54
Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ tiwọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn.
ואם לא תורישו את ישבי הארץ מפניכם והיה אשר תותירו מהם לשכים בעיניכם ולצנינם בצדיכם וצררו אתכם על הארץ אשר אתם ישבים בה׃ 55
“‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.
והיה כאשר דמיתי לעשות להם אעשה לכם׃ 56
Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’”

< במדבר 33 >