< יונה 2 >
ויתפלל יונה אל יהוה אלהיו ממעי הדגה׃ | 1 |
Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,
ויאמר קראתי מצרה לי אל יהוה ויענני מבטן שאול שועתי שמעת קולי׃ (Sheol ) | 2 |
Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi. (Sheol )
ותשליכני מצולה בלבב ימים ונהר יסבבני כל משבריך וגליך עלי עברו׃ | 3 |
Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.
ואני אמרתי נגרשתי מנגד עיניך אך אוסיף להביט אל היכל קדשך׃ | 4 |
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’
אפפוני מים עד נפש תהום יסבבני סוף חבוש לראשי׃ | 5 |
Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí.
לקצבי הרים ירדתי הארץ ברחיה בעדי לעולם ותעל משחת חיי יהוה אלהי׃ | 6 |
Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi.
בהתעטף עלי נפשי את יהוה זכרתי ותבוא אליך תפלתי אל היכל קדשך׃ | 7 |
“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.
משמרים הבלי שוא חסדם יעזבו׃ | 8 |
“Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀.
ואני בקול תודה אזבחה לך אשר נדרתי אשלמה ישועתה ליהוה׃ | 9 |
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’”
ויאמר יהוה לדג ויקא את יונה אל היבשה׃ | 10 |
Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.