< איוב 5 >

קרא נא היש עונך ואל מי מקדשים תפנה׃ 1
“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?
כי לאויל יהרג כעש ופתה תמית קנאה׃ 2
Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.
אני ראיתי אויל משריש ואקוב נוהו פתאם׃ 3
Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.
ירחקו בניו מישע וידכאו בשער ואין מציל׃ 4
Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.
אשר קצירו רעב יאכל ואל מצנים יקחהו ושאף צמים חילם׃ 5
Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.
כי לא יצא מעפר און ומאדמה לא יצמח עמל׃ 6
Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.
כי אדם לעמל יולד ובני רשף יגביהו עוף׃ 7
Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà, gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.
אולם אני אדרש אל אל ואל אלהים אשים דברתי׃ 8
“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
עשה גדלות ואין חקר נפלאות עד אין מספר׃ 9
Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye.
הנתן מטר על פני ארץ ושלח מים על פני חוצות׃ 10
Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.
לשום שפלים למרום וקדרים שגבו ישע׃ 11
Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.
מפר מחשבות ערומים ולא תעשינה ידיהם תושיה׃ 12
Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.
לכד חכמים בערמם ועצת נפתלים נמהרה׃ 13
Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.
יומם יפגשו חשך וכלילה ימששו בצהרים׃ 14
Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.
וישע מחרב מפיהם ומיד חזק אביון׃ 15
Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.
ותהי לדל תקוה ועלתה קפצה פיה׃ 16
Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà, àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
הנה אשרי אנוש יוכחנו אלוה ומוסר שדי אל תמאס׃ 17
“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.
כי הוא יכאיב ויחבש ימחץ וידו תרפינה׃ 18
Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
בשש צרות יצילך ובשבע לא יגע בך רע׃ 19
Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ.
ברעב פדך ממות ובמלחמה מידי חרב׃ 20
Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
בשוט לשון תחבא ולא תירא משד כי יבוא׃ 21
A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n, bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
לשד ולכפן תשחק ומחית הארץ אל תירא׃ 22
Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
כי עם אבני השדה בריתך וחית השדה השלמה לך׃ 23
Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
וידעת כי שלום אהלך ופקדת נוך ולא תחטא׃ 24
Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà, ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.
וידעת כי רב זרעך וצאצאיך כעשב הארץ׃ 25
Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.
תבוא בכלח אלי קבר כעלות גדיש בעתו׃ 26
Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.
הנה זאת חקרנוה כן היא שמענה ואתה דע לך׃ 27
“Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”

< איוב 5 >