< איוב 33 >
ואולם שמע נא איוב מלי וכל דברי האזינה׃ | 1 |
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
הנה נא פתחתי פי דברה לשוני בחכי׃ | 2 |
Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
ישר לבי אמרי ודעת שפתי ברור מללו׃ | 3 |
Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
רוח אל עשתני ונשמת שדי תחיני׃ | 4 |
Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi, àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.
אם תוכל השיבני ערכה לפני התיצבה׃ | 5 |
Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn, tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi;
הן אני כפיך לאל מחמר קרצתי גם אני׃ | 6 |
kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.
הנה אמתי לא תבעתך ואכפי עליך לא יכבד׃ | 7 |
Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ; bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.
אך אמרת באזני וקול מלין אשמע׃ | 8 |
“Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
זך אני בלי פשע חף אנכי ולא עון לי׃ | 9 |
‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi; bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
הן תנואות עלי ימצא יחשבני לאויב לו׃ | 10 |
Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi; ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
ישם בסד רגלי ישמר כל ארחתי׃ | 11 |
Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà; o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’
הן זאת לא צדקת אענך כי ירבה אלוה מאנוש׃ | 12 |
“Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà! Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
מדוע אליו ריבות כי כל דבריו לא יענה׃ | 13 |
Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
כי באחת ידבר אל ובשתים לא ישורנה׃ | 14 |
Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
בחלום חזיון לילה בנפל תרדמה על אנשים בתנומות עלי משכב׃ | 15 |
Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn,
אז יגלה אזן אנשים ובמסרם יחתם׃ | 16 |
nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
להסיר אדם מעשה וגוה מגבר יכסה׃ | 17 |
kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
יחשך נפשו מני שחת וחיתו מעבר בשלח׃ | 18 |
Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.
והוכח במכאוב על משכבו וריב עצמיו אתן׃ | 19 |
“A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
וזהמתו חיתו לחם ונפשו מאכל תאוה׃ | 20 |
bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
יכל בשרו מראי ושפי עצמותיו לא ראו׃ | 21 |
Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
ותקרב לשחת נפשו וחיתו לממתים׃ | 22 |
Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
אם יש עליו מלאך מליץ אחד מני אלף להגיד לאדם ישרו׃ | 23 |
Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
ויחננו ויאמר פדעהו מרדת שחת מצאתי כפר׃ | 24 |
nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú; èmi ti rà á padà.
רטפש בשרו מנער ישוב לימי עלומיו׃ | 25 |
Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
יעתר אל אלוה וירצהו וירא פניו בתרועה וישב לאנוש צדקתו׃ | 26 |
Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
ישר על אנשים ויאמר חטאתי וישר העויתי ולא שוה לי׃ | 27 |
Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé, ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
פדה נפשי מעבר בשחת וחיתי באור תראה׃ | 28 |
Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’
הן כל אלה יפעל אל פעמים שלוש עם גבר׃ | 29 |
“Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
להשיב נפשו מני שחת לאור באור החיים׃ | 30 |
láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.
הקשב איוב שמע לי החרש ואנכי אדבר׃ | 31 |
“Jobu, kíyèsi i gidigidi, kí o sì fetí sí mi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́.
אם יש מלין השיבני דבר כי חפצתי צדקך׃ | 32 |
Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn; máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
אם אין אתה שמע לי החרש ואאלפך חכמה׃ | 33 |
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”