< ישעה 54 >

רני עקרה לא ילדה פצחי רנה וצהלי לא חלה כי רבים בני שוממה מבני בעולה אמר יהוה׃ 1
“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni Olúwa wí.
הרחיבי מקום אהלך ויריעות משכנותיך יטו אל תחשכי האריכי מיתריך ויתדתיך חזקי׃ 2
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró; sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpó rẹ lágbára sí i.
כי ימין ושמאול תפרצי וזרעך גוים יירש וערים נשמות יושיבו׃ 3
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì; ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
אל תיראי כי לא תבושי ואל תכלמי כי לא תחפירי כי בשת עלומיך תשכחי וחרפת אלמנותיך לא תזכרי עוד׃ 4
“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ, ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
כי בעליך עשיך יהוה צבאות שמו וגאלך קדוש ישראל אלהי כל הארץ יקרא׃ 5
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
כי כאשה עזובה ועצובת רוח קראך יהוה ואשת נעורים כי תמאס אמר אלהיך׃ 6
Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí.
ברגע קטן עזבתיך וברחמים גדלים אקבצך׃ 7
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá.
בשצף קצף הסתרתי פני רגע ממך ובחסד עולם רחמתיך אמר גאלך יהוה׃ 8
Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.
כי מי נח זאת לי אשר נשבעתי מעבר מי נח עוד על הארץ כן נשבעתי מקצף עליך ומגער בך׃ 9
“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
כי ההרים ימושו והגבעות תמוטנה וחסדי מאתך לא ימוש וברית שלומי לא תמוט אמר מרחמך יהוה׃ 10
Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí, síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.
עניה סערה לא נחמה הנה אנכי מרביץ בפוך אבניך ויסדתיך בספירים׃ 11
Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri tí a kò sì tù nínú, Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
ושמתי כדכד שמשתיך ושעריך לאבני אקדח וכל גבולך לאבני חפץ׃ 12
Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ, àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
וכל בניך למודי יהוה ורב שלום בניך׃ 13
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
בצדקה תכונני רחקי מעשק כי לא תיראי וממחתה כי לא תקרב אליך׃ 14
Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ìpayà la ó mú kúrò pátápátá; kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
הן גור יגור אפס מאותי מי גר אתך עליך יפול׃ 15
Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
הן אנכי בראתי חרש נפח באש פחם ומוציא כלי למעשהו ואנכי בראתי משחית לחבל׃ 16
“Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
כל כלי יוצר עליך לא יצלח וכל לשון תקום אתך למשפט תרשיעי זאת נחלת עבדי יהוה וצדקתם מאתי נאם יהוה׃ 17
kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.

< ישעה 54 >

A Dove is Sent Forth from the Ark
A Dove is Sent Forth from the Ark