< יחזקאל 28 >
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃ | 1 |
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
בן אדם אמר לנגיד צר כה אמר אדני יהוה יען גבה לבך ותאמר אל אני מושב אלהים ישבתי בלב ימים ואתה אדם ולא אל ותתן לבך כלב אלהים׃ | 2 |
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
הנה חכם אתה מדנאל כל סתום לא עממוך׃ | 3 |
Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
בחכמתך ובתבונתך עשית לך חיל ותעש זהב וכסף באוצרותיך׃ | 4 |
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
ברב חכמתך ברכלתך הרבית חילך ויגבה לבבך בחילך׃ | 5 |
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.
לכן כה אמר אדני יהוה יען תתך את לבבך כלב אלהים׃ | 6 |
“‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
לכן הנני מביא עליך זרים עריצי גוים והריקו חרבותם על יפי חכמתך וחללו יפעתך׃ | 7 |
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
לשחת יורדוך ומתה ממותי חלל בלב ימים׃ | 8 |
Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná, àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
האמר תאמר אלהים אני לפני הרגך ואתה אדם ולא אל ביד מחלליך׃ | 9 |
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
מותי ערלים תמות ביד זרים כי אני דברתי נאם אדני יהוה׃ | 10 |
Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, ní ọwọ́ àwọn àjèjì. Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’”
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃ | 11 |
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
בן אדם שא קינה על מלך צור ואמרת לו כה אמר אדני יהוה אתה חותם תכנית מלא חכמה וכליל יפי׃ | 12 |
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà.
בעדן גן אלהים היית כל אבן יקרה מסכתך אדם פטדה ויהלם תרשיש שהם וישפה ספיר נפך וברקת וזהב מלאכת תפיך ונקביך בך ביום הבראך כוננו׃ | 13 |
Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ; sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì, àti jasperi, safire, emeradi, turikuose, àti karbunkili, àti wúrà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà, láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
את כרוב ממשח הסוכך ונתתיך בהר קדש אלהים היית בתוך אבני אש התהלכת׃ | 14 |
A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́. Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run; ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná.
תמים אתה בדרכיך מיום הבראך עד נמצא עולתה בך׃ | 15 |
Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí a ti dá ọ, títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
ברב רכלתך מלו תוכך חמס ותחטא ואחללך מהר אלהים ואבדך כרוב הסכך מתוך אבני אש׃ | 16 |
Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ, ìwọ kún fún ìwà ipá; ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù, bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run. Èmi sì pa ọ run, ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
גבה לבך ביפיך שחת חכמתך על יפעתך על ארץ השלכתיך לפני מלכים נתתיך לראוה בך׃ | 17 |
Ọkàn rẹ gbéraga, nítorí ẹwà rẹ. Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́, nítorí dídára rẹ. Nítorí náà mo le ọ sórí ayé; mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
מרב עוניך בעול רכלתך חללת מקדשיך ואוצא אש מתוכך היא אכלתך ואתנך לאפר על הארץ לעיני כל ראיך׃ | 18 |
Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ, ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́. Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá, láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run, èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀, lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
כל יודעיך בעמים שממו עליך בלהות היית ואינך עד עולם׃ | 19 |
Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n, ní ẹnu ń yà sí ọ; ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’”
ויהי דבר יהוה אלי לאמר׃ | 20 |
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
בן אדם שים פניך אל צידון והנבא עליה׃ | 21 |
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i,
ואמרת כה אמר אדני יהוה הנני עליך צידון ונכבדתי בתוכך וידעו כי אני יהוה בעשותי בה שפטים ונקדשתי בה׃ | 22 |
kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni, a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ, tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.
ושלחתי בה דבר ודם בחוצותיה ונפלל חלל בתוכה בחרב עליה מסביב וידעו כי אני יהוה׃ | 23 |
Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ, èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ, ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ, pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
ולא יהיה עוד לבית ישראל סלון ממאיר וקוץ מכאב מכל סביבתם השאטים אותם וידעו כי אני אדני יהוה׃ | 24 |
“‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.
כה אמר אדני יהוה בקבצי את בית ישראל מן העמים אשר נפצו בם ונקדשתי בם לעיני הגוים וישבו על אדמתם אשר נתתי לעבדי ליעקב׃ | 25 |
“‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu.
וישבו עליה לבטח ובנו בתים ונטעו כרמים וישבו לבטח בעשותי שפטים בכל השאטים אתם מסביבותם וידעו כי אני יהוה אלהיהם׃ | 26 |
Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’”