< שמות 33 >
וידבר יהוה אל משה לך עלה מזה אתה והעם אשר העלית מארץ מצרים אל הארץ אשר נשבעתי לאברהם ליצחק וליעקב לאמר לזרעך אתננה׃ | 1 |
Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’
ושלחתי לפניך מלאך וגרשתי את הכנעני האמרי והחתי והפרזי החוי והיבוסי׃ | 2 |
Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, Èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde.
אל ארץ זבת חלב ודבש כי לא אעלה בקרבך כי עם קשה ערף אתה פן אכלך בדרך׃ | 3 |
Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”
וישמע העם את הדבר הרע הזה ויתאבלו ולא שתו איש עדיו עליו׃ | 4 |
Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀.
ויאמר יהוה אל משה אמר אל בני ישראל אתם עם קשה ערף רגע אחד אעלה בקרבך וכליתיך ועתה הורד עדיך מעליך ואדעה מה אעשה לך׃ | 5 |
Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn Ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí Èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, Èmi lè pa yín run. Nísìnsinyìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, Èmi yóò sì gbèrò ohun tí Èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’”
ויתנצלו בני ישראל את עדים מהר חורב׃ | 6 |
Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu.
ומשה יקח את האהל ונטה לו מחוץ למחנה הרחק מן המחנה וקרא לו אהל מועד והיה כל מבקש יהוה יצא אל אהל מועד אשר מחוץ למחנה׃ | 7 |
Mose máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń béèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.
והיה כצאת משה אל האהל יקומו כל העם ונצבו איש פתח אהלו והביטו אחרי משה עד באו האהלה׃ | 8 |
Nígbàkígbà tí Mose bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mose títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà.
והיה כבא משה האהלה ירד עמוד הענן ועמד פתח האהל ודבר עם משה׃ | 9 |
Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose.
וראה כל העם את עמוד הענן עמד פתח האהל וקם כל העם והשתחוו איש פתח אהלו׃ | 10 |
Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.
ודבר יהוה אל משה פנים אל פנים כאשר ידבר איש אל רעהו ושב אל המחנה ומשרתו יהושע בן נון נער לא ימיש מתוך האהל׃ | 11 |
Olúwa máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.
ויאמר משה אל יהוה ראה אתה אמר אלי העל את העם הזה ואתה לא הודעתני את אשר תשלח עמי ואתה אמרת ידעתיך בשם וגם מצאת חן בעיני׃ | 12 |
Mose sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’
ועתה אם נא מצאתי חן בעיניך הודעני נא את דרכך ואדעך למען אמצא חן בעיניך וראה כי עמך הגוי הזה׃ | 13 |
Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”
ויאמר פני ילכו והנחתי לך׃ | 14 |
Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”
ויאמר אליו אם אין פניך הלכים אל תעלנו מזה׃ | 15 |
Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ.
ובמה יודע אפוא כי מצאתי חן בעיניך אני ועמך הלוא בלכתך עמנו ונפלינו אני ועמך מכל העם אשר על פני האדמה׃ | 16 |
Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”
ויאמר יהוה אל משה גם את הדבר הזה אשר דברת אעשה כי מצאת חן בעיני ואדעך בשם׃ | 17 |
Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, Èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”
ויאמר הראני נא את כבדך׃ | 18 |
Mose sì wí pé, “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”
ויאמר אני אעביר כל טובי על פניך וקראתי בשם יהוה לפניך וחנתי את אשר אחן ורחמתי את אשר ארחם׃ | 19 |
Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí Èmi yóò ṣàánú fún, Èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí Èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.
ויאמר לא תוכל לראת את פני כי לא יראני האדם וחי׃ | 20 |
Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.”
ויאמר יהוה הנה מקום אתי ונצבת על הצור׃ | 21 |
Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta.
והיה בעבר כבדי ושמתיך בנקרת הצור ושכתי כפי עליך עד עברי׃ | 22 |
Nígbà tí ògo mi bá kọjá, Èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, Èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí Èmi yóò fi rékọjá.
והסרתי את כפי וראית את אחרי ופני לא יראו׃ | 23 |
Nígbà tí Èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”