< מלכים א 13 >
והנה איש אלהים בא מיהודה בדבר יהוה אל בית אל וירבעם עמד על המזבח להקטיר׃ | 1 |
Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná.
ויקרא על המזבח בדבר יהוה ויאמר מזבח מזבח כה אמר יהוה הנה בן נולד לבית דוד יאשיהו שמו וזבח עליך את כהני הבמות המקטרים עליך ועצמות אדם ישרפו עליך׃ | 2 |
Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’”
ונתן ביום ההוא מופת לאמר זה המופת אשר דבר יהוה הנה המזבח נקרע ונשפך הדשן אשר עליו׃ | 3 |
Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”
ויהי כשמע המלך את דבר איש האלהים אשר קרא על המזבח בבית אל וישלח ירבעם את ידו מעל המזבח לאמר תפשהו ותיבש ידו אשר שלח עליו ולא יכל להשיבה אליו׃ | 4 |
Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un!” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́.
והמזבח נקרע וישפך הדשן מן המזבח כמופת אשר נתן איש האלהים בדבר יהוה׃ | 5 |
Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.
ויען המלך ויאמר אל איש האלהים חל נא את פני יהוה אלהיך והתפלל בעדי ותשב ידי אלי ויחל איש האלהים את פני יהוה ותשב יד המלך אליו ותהי כבראשנה׃ | 6 |
Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.
וידבר המלך אל איש האלהים באה אתי הביתה וסעדה ואתנה לך מתת׃ | 7 |
Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”
ויאמר איש האלהים אל המלך אם תתן לי את חצי ביתך לא אבא עמך ולא אכל לחם ולא אשתה מים במקום הזה׃ | 8 |
Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí.
כי כן צוה אתי בדבר יהוה לאמר לא תאכל לחם ולא תשתה מים ולא תשוב בדרך אשר הלכת׃ | 9 |
Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’”
וילך בדרך אחר ולא שב בדרך אשר בא בה אל בית אל׃ | 10 |
Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.
ונביא אחד זקן ישב בבית אל ויבוא בנו ויספר לו את כל המעשה אשר עשה איש האלהים היום בבית אל את הדברים אשר דבר אל המלך ויספרום לאביהם׃ | 11 |
Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Beteli, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Beteli ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba.
וידבר אלהם אביהם אי זה הדרך הלך ויראו בניו את הדרך אשר הלך איש האלהים אשר בא מיהודה׃ | 12 |
Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ọ̀nà wo ni ó gbà?” Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Juda gbà hàn án.
ויאמר אל בניו חבשו לי החמור ויחבשו לו החמור וירכב עליו׃ | 13 |
Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún.
וילך אחרי איש האלהים וימצאהו ישב תחת האלה ויאמר אליו האתה איש האלהים אשר באת מיהודה ויאמר אני׃ | 14 |
Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn. Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi óákù kan, ó sì wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá bí?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”
ויאמר אליו לך אתי הביתה ואכל לחם׃ | 15 |
Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, “Bá mi lọ ilé, kí o sì jẹun.”
ויאמר לא אוכל לשוב אתך ולבוא אתך ולא אכל לחם ולא אשתה אתך מים במקום הזה׃ | 16 |
Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, “Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn-ín.
כי דבר אלי בדבר יהוה לא תאכל לחם ולא תשתה שם מים לא תשוב ללכת בדרך אשר הלכת בה׃ | 17 |
A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’”
ויאמר לו גם אני נביא כמוך ומלאך דבר אלי בדבר יהוה לאמר השבהו אתך אל ביתך ויאכל לחם וישת מים כחש לו׃ | 18 |
Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Angẹli sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.)
וישב אתו ויאכל לחם בביתו וישת מים׃ | 19 |
Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.
ויהי הם ישבים אל השלחן ויהי דבר יהוה אל הנביא אשר השיבו׃ | 20 |
Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé;
ויקרא אל איש האלהים אשר בא מיהודה לאמר כה אמר יהוה יען כי מרית פי יהוה ולא שמרת את המצוה אשר צוך יהוה אלהיך׃ | 21 |
Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́.
ותשב ותאכל לחם ותשת מים במקום אשר דבר אליך אל תאכל לחם ואל תשת מים לא תבוא נבלתך אל קבר אבתיך׃ | 22 |
Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’”
ויהי אחרי אכלו לחם ואחרי שתותו ויחבש לו החמור לנביא אשר השיבו׃ | 23 |
Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un.
וילך וימצאהו אריה בדרך וימיתהו ותהי נבלתו משלכת בדרך והחמור עמד אצלה והאריה עמד אצל הנבלה׃ | 24 |
Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́.
והנה אנשים עברים ויראו את הנבלה משלכת בדרך ואת האריה עמד אצל הנבלה ויבאו וידברו בעיר אשר הנביא הזקן ישב בה׃ | 25 |
Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí pé ó gbé òkú náà sọ sí ojú ọ̀nà, kìnnìún náà sì dúró ti òkú náà; wọ́n sì wá, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé.
וישמע הנביא אשר השיבו מן הדרך ויאמר איש האלהים הוא אשר מרה את פי יהוה ויתנהו יהוה לאריה וישברהו וימתהו כדבר יהוה אשר דבר לו׃ | 26 |
Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́. Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un.”
וידבר אל בניו לאמר חבשו לי את החמור ויחבשו׃ | 27 |
Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.
וילך וימצא את נבלתו משלכת בדרך וחמור והאריה עמדים אצל הנבלה לא אכל האריה את הנבלה ולא שבר את החמור׃ | 28 |
Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya.
וישא הנביא את נבלת איש האלהים וינחהו אל החמור וישיבהו ויבא אל עיר הנביא הזקן לספד ולקברו׃ | 29 |
Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín.
וינח את נבלתו בקברו ויספדו עליו הוי אחי׃ | 30 |
Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”
ויהי אחרי קברו אתו ויאמר אל בניו לאמר במותי וקברתם אתי בקבר אשר איש האלהים קבור בו אצל עצמתיו הניחו את עצמתי׃ | 31 |
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀.
כי היה יהיה הדבר אשר קרא בדבר יהוה על המזבח אשר בבית אל ועל כל בתי הבמות אשר בערי שמרון׃ | 32 |
Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Beteli àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samaria yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.”
אחר הדבר הזה לא שב ירבעם מדרכו הרעה וישב ויעש מקצות העם כהני במות החפץ ימלא את ידו ויהי כהני במות׃ | 33 |
Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jeroboamu kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí.
ויהי בדבר הזה לחטאת בית ירבעם ולהכחיד ולהשמיד מעל פני האדמה׃ | 34 |
Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.