< דברי הימים א 18 >
ויהי אחרי כן ויך דויד את פלשתים ויכניעם ויקח את גת ובנתיה מיד פלשתים׃ | 1 |
Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini.
ויך את מואב ויהיו מואב עבדים לדויד נשאי מנחה׃ | 2 |
Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.
ויך דויד את הדדעזר מלך צובה חמתה בלכתו להציב ידו בנהר פרת׃ | 3 |
Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Soba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate.
וילכד דויד ממנו אלף רכב ושבעת אלפים פרשים ועשרים אלף איש רגלי ויעקר דויד את כל הרכב ויותר ממנו מאה רכב׃ | 4 |
Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.
ויבא ארם דרמשק לעזור להדדעזר מלך צובה ויך דויד בארם עשרים ושנים אלף איש׃ | 5 |
Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbẹ̀rún méjìlélógún wọn bọ lẹ̀.
וישם דויד בארם דרמשק ויהי ארם לדויד עבדים נשאי מנחה ויושע יהוה לדויד בכל אשר הלך׃ | 6 |
Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.
ויקח דויד את שלטי הזהב אשר היו על עבדי הדדעזר ויביאם ירושלם׃ | 7 |
Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu.
ומטבחת ומכון ערי הדדעזר לקח דויד נחשת רבה מאד בה עשה שלמה את ים הנחשת ואת העמודים ואת כלי הנחשת׃ | 8 |
Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.
וישמע תעו מלך חמת כי הכה דויד את כל חיל הדדעזר מלך צובה׃ | 9 |
Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba.
וישלח את הדורם בנו אל המלך דויד לשאול לו לשלום ולברכו על אשר נלחם בהדדעזר ויכהו כי איש מלחמות תעו היה הדדעזר וכל כלי זהב וכסף ונחשת׃ | 10 |
Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá.
גם אתם הקדיש המלך דויד ליהוה עם הכסף והזהב אשר נשא מכל הגוים מאדום וממואב ומבני עמון ומפלשתים ומעמלק׃ | 11 |
Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.
ואבשי בן צרויה הכה את אדום בגיא המלח שמונה עשר אלף׃ | 12 |
Abiṣai ọmọ Seruiah lu ẹgbàá mẹ́sàn ará Edomu bolẹ̀ ní àfonífojì Iyọ̀.
וישם באדום נציבים ויהיו כל אדום עבדים לדויד ויושע יהוה את דויד בכל אשר הלך׃ | 13 |
Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. Olúwa fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.
וימלך דויד על כל ישראל ויהי עשה משפט וצדקה לכל עמו׃ | 14 |
Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.
ויואב בן צרויה על הצבא ויהושפט בן אחילוד מזכיר׃ | 15 |
Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;
וצדוק בן אחיטוב ואבימלך בן אביתר כהנים ושושא סופר׃ | 16 |
Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé;
ובניהו בן יהוידע על הכרתי והפלתי ובני דויד הראשנים ליד המלך׃ | 17 |
Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti; àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.