< תְהִלִּים 61 >
לַמְנַצֵּ֬חַ ׀ עַֽל־נְגִינַ֬ת לְדָוִֽד׃ שִׁמְעָ֣ה אֱ֭לֹהִים רִנָּתִ֑י הַ֝קְשִׁ֗יבָה תְּפִלָּתִֽי׃ | 1 |
Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi.
מִקְצֵ֤ה הָאָ֨רֶץ ׀ אֵלֶ֣יךָ אֶ֭קְרָא בַּעֲטֹ֣ף לִבִּ֑י בְּצוּר־יָר֖וּם מִמֶּ֣נִּי תַנְחֵֽנִי׃ | 2 |
Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
כִּֽי־הָיִ֣יתָ מַחְסֶ֣ה לִ֑י מִגְדַּל־עֹ֝֗ז מִפְּנֵ֥י אוֹיֵֽב׃ | 3 |
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
אָג֣וּרָה בְ֭אָהָלְךָ עוֹלָמִ֑ים אֶֽחֱסֶ֨ה בְסֵ֖תֶר כְּנָפֶ֣יךָ סֶּֽלָה׃ | 4 |
Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
כִּֽי־אַתָּ֣ה אֱ֭לֹהִים שָׁמַ֣עְתָּ לִנְדָרָ֑י נָתַ֥תָּ יְ֝רֻשַּׁ֗ת יִרְאֵ֥י שְׁמֶֽךָ׃ | 5 |
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
יָמִ֣ים עַל־יְמֵי־מֶ֣לֶךְ תּוֹסִ֑יף שְׁ֝נוֹתָ֗יו כְּמוֹ־דֹ֥ר וָדֹֽר׃ | 6 |
Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
יֵשֵׁ֣ב ע֭וֹלָם לִפְנֵ֣י אֱלֹהִ֑ים חֶ֥סֶד וֶ֝אֱמֶ֗ת מַ֣ן יִנְצְרֻֽהוּ׃ | 7 |
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
כֵּ֤ן אֲזַמְּרָ֣ה שִׁמְךָ֣ לָעַ֑ד לְֽשַׁלְּמִ֥י נְדָרַ֗י י֣וֹם ׀ יֽוֹם׃ | 8 |
Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.