< תְהִלִּים 25 >
לְדָוִ֡ד אֵלֶ֥יךָ יְ֝הוָ֗ה נַפְשִׁ֥י אֶשָּֽׂא׃ | 1 |
Ti Dafidi. Olúwa, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
אֱֽלֹהַ֗י בְּךָ֣ בָ֭טַחְתִּי אַל־אֵב֑וֹשָׁה אַל־יַֽעַלְצ֖וּ אֹיְבַ֣י לִֽי׃ | 2 |
Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
גַּ֣ם כָּל־קֹ֭וֶיךָ לֹ֣א יֵבֹ֑שׁוּ יֵ֝בֹ֗שׁוּ הַבּוֹגְדִ֥ים רֵיקָֽם׃ | 3 |
Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì.
דְּרָכֶ֣יךָ יְ֭הוָה הוֹדִיעֵ֑נִי אֹ֖רְחוֹתֶ֣יךָ לַמְּדֵֽנִי׃ | 4 |
Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa, kọ mi ní ipa tìrẹ;
הַדְרִ֘יכֵ֤נִי בַאֲמִתֶּ֨ךָ ׀ וְֽלַמְּדֵ֗נִי כִּֽי־אַ֭תָּה אֱלֹהֵ֣י יִשְׁעִ֑י אוֹתְךָ֥ קִ֝וִּ֗יתִי כָּל־הַיּֽוֹם׃ | 5 |
ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
זְכֹר־רַחֲמֶ֣יךָ יְ֭הוָה וַחֲסָדֶ֑יךָ כִּ֖י מֵעוֹלָ֣ם הֵֽמָּה׃ | 6 |
Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.
חַטֹּ֤אות נְעוּרַ֨י ׀ וּפְשָׁעַ֗י אַל־תִּ֫זְכֹּ֥ר כְּחַסְדְּךָ֥ זְכָר־לִי־אַ֑תָּה לְמַ֖עַן טוּבְךָ֣ יְהוָֽה׃ | 7 |
Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjá mi; gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
טוֹב־וְיָשָׁ֥ר יְהוָ֑ה עַל־כֵּ֤ן יוֹרֶ֖ה חַטָּאִ֣ים בַּדָּֽרֶךְ׃ | 8 |
Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa: nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
יַדְרֵ֣ךְ עֲ֭נָוִים בַּמִּשְׁפָּ֑ט וִֽילַמֵּ֖ד עֲנָוִ֣ים דַּרְכּֽוֹ׃ | 9 |
Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
כָּל־אָרְח֣וֹת יְ֭הוָה חֶ֣סֶד וֶאֱמֶ֑ת לְנֹצְרֵ֥י בְ֝רִית֗וֹ וְעֵדֹתָֽיו׃ | 10 |
Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
לְמַֽעַן־שִׁמְךָ֥ יְהוָ֑ה וְֽסָלַחְתָּ֥ לַ֝עֲוֺנִ֗י כִּ֣י רַב־הֽוּא׃ | 11 |
Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
מִי־זֶ֣ה הָ֭אִישׁ יְרֵ֣א יְהוָ֑ה י֝וֹרֶ֗נּוּ בְּדֶ֣רֶךְ יִבְחָֽר׃ | 12 |
Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
נַ֭פְשׁוֹ בְּט֣וֹב תָּלִ֑ין וְ֝זַרְע֗וֹ יִ֣ירַשׁ אָֽרֶץ׃ | 13 |
Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
ס֣וֹד יְ֭הוָה לִירֵאָ֑יו וּ֝בְרִית֗וֹ לְהוֹדִיעָֽם׃ | 14 |
Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
עֵינַ֣י תָּ֭מִיד אֶל־יְהוָ֑ה כִּ֤י הֽוּא־יוֹצִ֖יא מֵרֶ֣שֶׁת רַגְלָֽי׃ | 15 |
Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
פְּנֵה־אֵלַ֥י וְחָנֵּ֑נִי כִּֽי־יָחִ֖יד וְעָנִ֣י אָֽנִי׃ | 16 |
Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
צָר֣וֹת לְבָבִ֣י הִרְחִ֑יבוּ מִ֝מְּצֽוּקוֹתַ֗י הוֹצִיאֵֽנִי׃ | 17 |
Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
רְאֵ֣ה עָ֭נְיִי וַעֲמָלִ֑י וְ֝שָׂ֗א לְכָל־חַטֹּאותָֽי׃ | 18 |
Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
רְאֵֽה־אוֹיְבַ֥י כִּי־רָ֑בּוּ וְשִׂנְאַ֖ת חָמָ֣ס שְׂנֵאֽוּנִי׃ | 19 |
Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
שָׁמְרָ֣ה נַ֭פְשִׁי וְהַצִּילֵ֑נִי אַל־אֵ֝ב֗וֹשׁ כִּֽי־חָסִ֥יתִי בָֽךְ׃ | 20 |
Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
תֹּם־וָיֹ֥שֶׁר יִצְּר֑וּנִי כִּ֝֗י קִוִּיתִֽיךָ׃ | 21 |
Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́.
פְּדֵ֣ה אֱ֭לֹהִים אֶת־יִשְׂרָאֵ֑ל מִ֝כֹּ֗ל צָֽרוֹתָיו׃ | 22 |
Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!