< אֶסְתֵר 7 >
וַיָּבֹ֤א הַמֶּ֙לֶךְ֙ וְהָמָ֔ן לִשְׁתּ֖וֹת עִם־אֶסְתֵּ֥ר הַמַּלְכָּֽה׃ | 1 |
Ọba àti Hamani sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Esteri ayaba,
וַיֹּאמֶר֩ הַמֶּ֨לֶךְ לְאֶסְתֵּ֜ר גַּ֣ם בַּיּ֤וֹם הַשֵּׁנִי֙ בְּמִשְׁתֵּ֣ה הַיַּ֔יִן מַה־שְּׁאֵלָתֵ֛ךְ אֶסְתֵּ֥ר הַמַּלְכָּ֖ה וְתִנָּ֣תֵֽן לָ֑ךְ וּמַה־בַּקָּשָׁתֵ֛ךְ עַד־חֲצִ֥י הַמַּלְכ֖וּת וְתֵעָֽשׂ׃ | 2 |
bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.”
וַתַּ֨עַן אֶסְתֵּ֤ר הַמַּלְכָּה֙ וַתֹּאמַ֔ר אִם־מָצָ֨אתִי חֵ֤ן בְּעֵינֶ֙יךָ֙ הַמֶּ֔לֶךְ וְאִם־עַל־הַמֶּ֖לֶךְ ט֑וֹב תִּנָּֽתֶן־לִ֤י נַפְשִׁי֙ בִּשְׁאֵ֣לָתִ֔י וְעַמִּ֖י בְּבַקָּשָׁתִֽי׃ | 3 |
Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi.
כִּ֤י נִמְכַּ֙רְנוּ֙ אֲנִ֣י וְעַמִּ֔י לְהַשְׁמִ֖יד לַהֲר֣וֹג וּלְאַבֵּ֑ד וְ֠אִלּוּ לַעֲבָדִ֨ים וְלִשְׁפָח֤וֹת נִמְכַּ֙רְנוּ֙ הֶחֱרַ֔שְׁתִּי כִּ֣י אֵ֥ין הַצָּ֛ר שֹׁוֶ֖ה בְּנֵ֥זֶק הַמֶּֽלֶךְ׃ ס | 4 |
Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá tilẹ̀ tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹ bá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”
וַיֹּ֙אמֶר֙ הַמֶּ֣לֶךְ אֲחַשְׁוֵר֔וֹשׁ וַיֹּ֖אמֶר לְאֶסְתֵּ֣ר הַמַּלְכָּ֑ה מִ֣י ה֥וּא זֶה֙ וְאֵֽי־זֶ֣ה ה֔וּא אֲשֶׁר־מְלָא֥וֹ לִבּ֖וֹ לַעֲשׂ֥וֹת כֵּֽן׃ | 5 |
Ọba Ahaswerusi bi Esteri ayaba léèrè pé, “Ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?”
וַתֹּ֣אמֶר־אֶסְתֵּ֔ר אִ֚ישׁ צַ֣ר וְאוֹיֵ֔ב הָמָ֥ן הָרָ֖ע הַזֶּ֑ה וְהָמָ֣ן נִבְעַ֔ת מִלִּפְנֵ֥י הַמֶּ֖לֶךְ וְהַמַּלְכָּֽה׃ | 6 |
Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni Hamani aláìníláárí yìí.” Nígbà náà ni Hamani wárìrì níwájú ọba àti ayaba.
וְהַמֶּ֜לֶךְ קָ֤ם בַּחֲמָתוֹ֙ מִמִּשְׁתֵּ֣ה הַיַּ֔יִן אֶל־גִּנַּ֖ת הַבִּיתָ֑ן וְהָמָ֣ן עָמַ֗ד לְבַקֵּ֤שׁ עַל־נַפְשׁוֹ֙ מֵֽאֶסְתֵּ֣ר הַמַּלְכָּ֔ה כִּ֣י רָאָ֔ה כִּֽי־כָלְתָ֥ה אֵלָ֛יו הָרָעָ֖ה מֵאֵ֥ת הַמֶּֽלֶךְ׃ | 7 |
Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀.
וְהַמֶּ֡לֶךְ שָׁב֩ מִגִּנַּ֨ת הַבִּיתָ֜ן אֶל־בֵּ֣ית ׀ מִשְׁתֵּ֣ה הַיַּ֗יִן וְהָמָן֙ נֹפֵ֔ל עַל־הַמִּטָּה֙ אֲשֶׁ֣ר אֶסְתֵּ֣ר עָלֶ֔יהָ וַיֹּ֣אמֶר הַמֶּ֔לֶךְ הֲ֠גַם לִכְבּ֧וֹשׁ אֶת־הַמַּלְכָּ֛ה עִמִּ֖י בַּבָּ֑יִת הַדָּבָ֗ר יָצָא֙ מִפִּ֣י הַמֶּ֔לֶךְ וּפְנֵ֥י הָמָ֖ן חָפֽוּ׃ ס | 8 |
Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú.
וַיֹּ֣אמֶר חַ֠רְבוֹנָה אֶחָ֨ד מִן־הַסָּרִיסִ֜ים לִפְנֵ֣י הַמֶּ֗לֶךְ גַּ֣ם הִנֵּה־הָעֵ֣ץ אֲשֶׁר־עָשָׂ֪ה הָמָ֟ן לְֽמָרְדֳּכַ֞י אֲשֶׁ֧ר דִּבֶּר־ט֣וֹב עַל־הַמֶּ֗לֶךְ עֹמֵד֙ בְּבֵ֣ית הָמָ֔ן גָּבֹ֖הַּ חֲמִשִּׁ֣ים אַמָּ֑ה וַיֹּ֥אמֶר הַמֶּ֖לֶךְ תְּלֻ֥הוּ עָלָֽיו׃ | 9 |
Nígbà náà Harbona ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “Igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni Hamani ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún Mordekai, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.” Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́!
וַיִּתְלוּ֙ אֶת־הָמָ֔ן עַל־הָעֵ֖ץ אֲשֶׁר־הֵכִ֣ין לְמָרְדֳּכָ֑י וַחֲמַ֥ת הַמֶּ֖לֶךְ שָׁכָֽכָה׃ פ | 10 |
Wọ́n sì so Hamani sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Mordekai, ìbínú ọba sì rọ̀.