< תהילים 69 >
לַמְנַצֵּחַ עַֽל־שׁוֹשַׁנִּים לְדָוִֽד׃ הוֹשִׁיעֵנִי אֱלֹהִים כִּי בָאוּ מַיִם עַד־נָֽפֶשׁ׃ | 1 |
Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi. Gbà mí, Ọlọ́run, nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
טָבַעְתִּי ׀ בִּיוֵן מְצוּלָה וְאֵין מָעֳמָד בָּאתִי בְמַעֲמַקֵּי־מַיִם וְשִׁבֹּלֶת שְׁטָפָֽתְנִי׃ | 2 |
Mo ń rì nínú irà jíjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jíjìn; ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
יָגַעְתִּי בְקָרְאִי נִחַר גְּרוֹנִי כָּלוּ עֵינַי מְיַחֵל לֵאלֹהָֽי׃ | 3 |
Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
רַבּוּ ׀ מִשַּׂעֲרוֹת רֹאשִׁי שֹׂנְאַי חִנָּם עָצְמוּ מַצְמִיתַי אֹיְבַי שֶׁקֶר אֲשֶׁר לֹא־גָזַלְתִּי אָז אָשִֽׁיב׃ | 4 |
Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọ́n ju irun orí mi lọ, púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run. A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.
אֱֽלֹהִים אַתָּה יָדַעְתָּ לְאִוַּלְתִּי וְאַשְׁמוֹתַי מִמְּךָ לֹא־נִכְחָֽדוּ׃ | 5 |
Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
אַל־יֵבֹשׁוּ בִי ׀ קֹוֶיךָ אֲדֹנָי יְהוִה צְבָאוֹת אַל־יִכָּלְמוּ בִי מְבַקְשֶׁיךָ אֱלֹהֵי יִשְׂרָאֵֽל׃ | 6 |
Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun; má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Israẹli.
כִּֽי־עָלֶיךָ נָשָׂאתִי חֶרְפָּה כִּסְּתָה כְלִמָּה פָנָֽי׃ | 7 |
Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.
מוּזָר הָיִיתִי לְאֶחָי וְנָכְרִי לִבְנֵי אִמִּֽי׃ | 8 |
Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi; àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
כִּֽי־קִנְאַת בֵּיתְךָ אֲכָלָתְנִי וְחֶרְפּוֹת חוֹרְפֶיךָ נָפְלוּ עָלָֽי׃ | 9 |
nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
וָאֶבְכֶּה בַצּוֹם נַפְשִׁי וַתְּהִי לַחֲרָפוֹת לִֽי׃ | 10 |
Nígbà tí mo sọkún tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
וָאֶתְּנָה לְבוּשִׁי שָׂק וָאֱהִי לָהֶם לְמָשָֽׁל׃ | 11 |
nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
יָשִׂיחוּ בִי יֹשְׁבֵי שָׁעַר וּנְגִינוֹת שׁוֹתֵי שֵׁכָֽר׃ | 12 |
Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.
וַאֲנִי תְפִלָּתִֽי־לְךָ ׀ יְהוָה עֵת רָצוֹן אֱלֹהִים בְּרָב־חַסְדֶּךָ עֲנֵנִי בֶּאֱמֶת יִשְׁעֶֽךָ׃ | 13 |
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ, dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
הַצִּילֵנִי מִטִּיט וְאַל־אֶטְבָּעָה אִנָּצְלָה מִשֹּֽׂנְאַי וּמִמַּֽעֲמַקֵּי־מָֽיִם׃ | 14 |
Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀, má ṣe jẹ́ kí n rì; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, kúrò nínú ibú omi.
אַל־תִּשְׁטְפֵנִי ׀ שִׁבֹּלֶת מַיִם וְאַל־תִּבְלָעֵנִי מְצוּלָה וְאַל־תֶּאְטַר־עָלַי בְּאֵר פִּֽיהָ׃ | 15 |
Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.
עֲנֵנִי יְהוָה כִּי־טוֹב חַסְדֶּךָ כְּרֹב רַחֲמֶיךָ פְּנֵה אֵלָֽי׃ | 16 |
Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
וְאַל־תַּסְתֵּר פָּנֶיךָ מֵֽעַבְדֶּךָ כִּֽי־צַר־לִי מַהֵר עֲנֵֽנִי׃ | 17 |
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
קָרְבָה אֶל־נַפְשִׁי גְאָלָהּ לְמַעַן אֹיְבַי פְּדֵֽנִי׃ | 18 |
Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là; rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.
אַתָּה יָדַעְתָּ חֶרְפָּתִי וּבָשְׁתִּי וּכְלִמָּתִי נֶגְדְּךָ כָּל־צוֹרְרָֽי׃ | 19 |
Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá; gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
חֶרְפָּה ׀ שָֽׁבְרָה לִבִּי וָֽאָנוּשָׁה וָאֲקַוֶּה לָנוּד וָאַיִן וְלַמְנַחֲמִים וְלֹא מָצָֽאתִי׃ | 20 |
Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.
וַיִּתְּנוּ בְּבָרוּתִי רֹאשׁ וְלִצְמָאִי יַשְׁקוּנִי חֹֽמֶץ׃ | 21 |
Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi, àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.
יְהִֽי־שֻׁלְחָנָם לִפְנֵיהֶם לְפָח וְלִשְׁלוֹמִים לְמוֹקֵֽשׁ׃ | 22 |
Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.
תֶּחְשַׁכְנָה עֵינֵיהֶם מֵרְאוֹת וּמָתְנֵיהֶם תָּמִיד הַמְעַֽד׃ | 23 |
Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran, kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.
שְׁפָךְ־עֲלֵיהֶם זַעְמֶךָ וַחֲרוֹן אַפְּךָ יַשִּׂיגֵֽם׃ | 24 |
Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
תְּהִי־טִֽירָתָם נְשַׁמָּה בְּאָהֳלֵיהֶם אַל־יְהִי יֹשֵֽׁב׃ | 25 |
Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.
כִּֽי־אַתָּה אֲשֶׁר־הִכִּיתָ רָדָפוּ וְאֶל־מַכְאוֹב חֲלָלֶיךָ יְסַפֵּֽרוּ׃ | 26 |
Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.
תְּֽנָה־עָוֺן עַל־עֲוֺנָם וְאַל־יָבֹאוּ בְּצִדְקָתֶֽךָ׃ | 27 |
Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.
יִמָּחֽוּ מִסֵּפֶר חַיִּים וְעִם צַדִּיקִים אַל־יִכָּתֵֽבוּ׃ | 28 |
Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.
וַאֲנִי עָנִי וְכוֹאֵב יְשׁוּעָתְךָ אֱלֹהִים תְּשַׂגְּבֵֽנִי׃ | 29 |
Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.
אֲהַֽלְלָה שֵׁם־אֱלֹהִים בְּשִׁיר וַאֲגַדְּלֶנּוּ בְתוֹדָֽה׃ | 30 |
Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
וְתִיטַב לַֽיהוָה מִשּׁוֹר פָּר מַקְרִן מַפְרִֽיס׃ | 31 |
Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
רָאוּ עֲנָוִים יִשְׂמָחוּ דֹּרְשֵׁי אֱלֹהִים וִיחִי לְבַבְכֶֽם׃ | 32 |
Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
כִּֽי־שֹׁמֵעַ אֶל־אֶבְיוֹנִים יְהוָה וְאֶת־אֲסִירָיו לֹא בָזָֽה׃ | 33 |
Olúwa, gbọ́ ti aláìní, kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.
יְֽהַלְלוּהוּ שָׁמַיִם וָאָרֶץ יַמִּים וְֽכָל־רֹמֵשׂ בָּֽם׃ | 34 |
Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
כִּי אֱלֹהִים ׀ יוֹשִׁיעַ צִיּוֹן וְיִבְנֶה עָרֵי יְהוּדָה וְיָשְׁבוּ שָׁם וִירֵשֽׁוּהָ׃ | 35 |
nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;
וְזֶרַע עֲבָדָיו יִנְחָלוּהָ וְאֹהֲבֵי שְׁמוֹ יִשְׁכְּנוּ־בָֽהּ׃ | 36 |
àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.