< תהילים 131 >

שִׁיר הַֽמַּֽעֲלוֹת לְדָוִד יְהוָה ׀ לֹא־גָבַהּ לִבִּי וְלֹא־רָמוּ עֵינַי וְלֹֽא־הִלַּכְתִּי ׀ בִּגְדֹלוֹת וּבְנִפְלָאוֹת מִמֶּֽנִּי׃ 1
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.
אִם־לֹא שִׁוִּיתִי ׀ וְדוֹמַמְתִּי נַפְשִׁי כְּגָמֻל עֲלֵי אִמּוֹ כַּגָּמֻל עָלַי נַפְשִֽׁי׃ 2
Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú: ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
יַחֵל יִשְׂרָאֵל אֶל־יְהוָה מֵֽעַתָּה וְעַד־עוֹלָֽם׃ 3
Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.

< תהילים 131 >