< תְהִלִּים 106 >
הַֽלְלוּיָ֨הּ ׀ הֹוד֣וּ לַיהוָ֣ה כִּי־טֹ֑וב כִּ֖י לְעֹולָ֣ם חַסְדֹּֽו׃ | 1 |
Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
מִ֗י יְ֭מַלֵּל גְּבוּרֹ֣ות יְהוָ֑ה יַ֝שְׁמִ֗יעַ כָּל־תְּהִלָּתֹֽו׃ | 2 |
Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
אַ֭שְׁרֵי שֹׁמְרֵ֣י מִשְׁפָּ֑ט עֹשֵׂ֖ה צְדָקָ֣ה בְכָל־עֵֽת׃ | 3 |
Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.
זָכְרֵ֣נִי יְ֭הוָה בִּרְצֹ֣ון עַמֶּ֑ךָ פָּ֝קְדֵ֗נִי בִּישׁוּעָתֶֽךָ׃ | 4 |
Rántí mi, Olúwa, nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
לִרְאֹ֤ות ׀ בְּטֹ֘ובַ֤ת בְּחִירֶ֗יךָ לִ֭שְׂמֹחַ בְּשִׂמְחַ֣ת גֹּויֶ֑ךָ לְ֝הִתְהַלֵּ֗ל עִם־נַחֲלָתֶֽךָ׃ | 5 |
kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
חָטָ֥אנוּ עִם־אֲבֹותֵ֗ינוּ הֶעֱוִ֥ינוּ הִרְשָֽׁעְנוּ׃ | 6 |
Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe, àwa ti ṣe ohun tí kò dá a, a sì ti hùwà búburú.
אֲבֹ֘ותֵ֤ינוּ בְמִצְרַ֨יִם ׀ לֹא־הִשְׂכִּ֬ילוּ נִפְלְאֹותֶ֗יךָ לֹ֣א זָ֭כְרוּ אֶת־רֹ֣ב חֲסָדֶ֑יךָ וַיַּמְר֖וּ עַל־יָ֣ם בְּיַם־סֽוּף׃ | 7 |
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.
וַֽ֭יֹּושִׁיעֵם לְמַ֣עַן שְׁמֹ֑ו לְ֝הֹודִ֗יעַ אֶת־גְּבוּרָתֹֽו׃ | 8 |
Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.
וַיִּגְעַ֣ר בְּיַם־ס֭וּף וֽ͏ַיֶּחֱרָ֑ב וַיֹּולִיכֵ֥ם בַּ֝תְּהֹמֹ֗ות כַּמִּדְבָּֽר׃ | 9 |
O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.
וַֽ֭יֹּושִׁיעֵם מִיַּ֣ד שֹׂונֵ֑א וַ֝יִּגְאָלֵ֗ם מִיַּ֥ד אֹויֵֽב׃ | 10 |
O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.
וַיְכַסּוּ־מַ֥יִם צָרֵיהֶ֑ם אֶחָ֥ד מֵ֝הֶ֗ם לֹ֣א נֹותָֽר׃ | 11 |
Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
וַיַּאֲמִ֥ינוּ בִדְבָרָ֑יו יָ֝שִׁ֗ירוּ תְּהִלָּתֹֽו׃ | 12 |
Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
מִֽ֭הֲרוּ שָׁכְח֣וּ מַעֲשָׂ֑יו לֹֽא־חִ֝כּ֗וּ לַעֲצָתֹֽו׃ | 13 |
Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.
וַיִּתְאַוּ֣וּ תַ֭אֲוָה בַּמִּדְבָּ֑ר וַיְנַסּוּ־אֵ֝֗ל בִּֽישִׁימֹֽון׃ | 14 |
Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.
וַיִּתֵּ֣ן לָ֭הֶם שֶׁאֱלָתָ֑ם וַיְשַׁלַּ֖ח רָזֹ֣ון בְּנַפְשָֽׁם׃ | 15 |
Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
וַיְקַנְא֣וּ לְ֭מֹשֶׁה בַּֽמַּחֲנֶ֑ה לְ֝אַהֲרֹ֗ן קְדֹ֣ושׁ יְהוָֽה׃ | 16 |
Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
תִּפְתַּח־אֶ֭רֶץ וַתִּבְלַ֣ע דָּתָ֑ן וַ֝תְּכַ֗ס עַל־עֲדַ֥ת אֲבִירָֽם׃ | 17 |
Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.
וַתִּבְעַר־אֵ֥שׁ בַּעֲדָתָ֑ם לֶ֝הָבָ֗ה תְּלַהֵ֥ט רְשָׁעִֽים׃ | 18 |
Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú.
יַעֲשׂוּ־עֵ֥גֶל בְּחֹרֵ֑ב וַ֝יִּשְׁתַּחֲו֗וּ לְמַסֵּכָֽה׃ | 19 |
Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
וַיָּמִ֥ירוּ אֶת־כְּבֹודָ֑ם בְּתַבְנִ֥ית שֹׁ֝֗ור אֹכֵ֥ל עֵֽשֶׂב׃ | 20 |
Wọ́n pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
שָׁ֭כְחוּ אֵ֣ל מֹושִׁיעָ֑ם עֹשֶׂ֖ה גְדֹלֹ֣ות בְּמִצְרָֽיִם׃ | 21 |
Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
נִ֭פְלָאֹות בְּאֶ֣רֶץ חָ֑ם נֹ֝ורָאֹ֗ות עַל־יַם־סֽוּף׃ | 22 |
iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.
וַיֹּ֗אמֶר לְֽהַשְׁמִ֫ידָ֥ם לוּלֵ֡י מֹ֘שֶׁ֤ה בְחִירֹ֗ו עָמַ֣ד בַּפֶּ֣רֶץ לְפָנָ֑יו לְהָשִׁ֥יב חֲ֝מָתֹ֗ו מֵֽהַשְׁחִֽית׃ | 23 |
Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
וַֽ֭יִּמְאֲסוּ בְּאֶ֣רֶץ חֶמְדָּ֑ה לֹֽא־הֶ֝אֱמִ֗ינוּ לִדְבָרֹֽו׃ | 24 |
Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
וַיֵּרָגְנ֥וּ בְאָהֳלֵיהֶ֑ם לֹ֥א שָׁ֝מְע֗וּ בְּקֹ֣ול יְהוָֽה׃ | 25 |
Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
וַיִּשָּׂ֣א יָדֹ֣ו לָהֶ֑ם לְהַפִּ֥יל אֹ֝ותָ֗ם בַּמִּדְבָּֽר׃ | 26 |
Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
וּלְהַפִּ֣יל זַ֭רְעָם בַּגֹּויִ֑ם וּ֝לְזָרֹותָ֗ם בָּאֲרָצֹֽות׃ | 27 |
láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
וַ֭יִּצָּ֣מְדוּ לְבַ֣עַל פְּעֹ֑ור וַ֝יֹּאכְל֗וּ זִבְחֵ֥י מֵתִֽים׃ | 28 |
Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,
וַ֭יַּכְעִיסוּ בְּמַֽעַלְלֵיהֶ֑ם וַתִּפְרָץ־בָּ֝֗ם מַגֵּפָֽה׃ | 29 |
wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
וַיַּעֲמֹ֣ד פִּֽ֭ינְחָס וַיְפַלֵּ֑ל וַ֝תֵּעָצַ֗ר הַמַּגֵּפָֽה׃ | 30 |
Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.
וַתֵּחָ֣שֶׁב לֹ֭ו לִצְדָקָ֑ה לְדֹ֥ר וָ֝דֹ֗ר עַד־עֹולָֽם׃ | 31 |
A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
וַ֭יַּקְצִיפוּ עַל־מֵ֥י מְרִיבָ֑ה וַיֵּ֥רַע לְ֝מֹשֶׁ֗ה בַּעֲבוּרָֽם׃ | 32 |
Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
כִּֽי־הִמְר֥וּ אֶת־רוּחֹ֑ו וַ֝יְבַטֵּ֗א בִּשְׂפָתָֽיו׃ | 33 |
Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
לֹֽא־הִ֭שְׁמִידוּ אֶת־הָֽעַמִּ֑ים אֲשֶׁ֤ר אָמַ֖ר יְהוָ֣ה לָהֶֽם׃ | 34 |
Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún wọn,
וַיִּתְעָרְב֥וּ בַגֹּויִ֑ם וַֽ֝יִּלְמְד֗וּ מַֽעֲשֵׂיהֶֽם׃ | 35 |
Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.
וַיַּעַבְד֥וּ אֶת־עֲצַבֵּיהֶ֑ם וַיִּהְי֖וּ לָהֶ֣ם לְמֹוקֵֽשׁ׃ | 36 |
Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
וַיִּזְבְּח֣וּ אֶת־בְּ֭נֵיהֶם וְאֶת־בְּנֹֽותֵיהֶ֗ם לַשֵּֽׁדִים׃ | 37 |
Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
וַיִּֽשְׁפְּכ֨וּ דָ֪ם נָקִ֡י דַּם־בְּנֵ֘יהֶ֤ם וּֽבְנֹותֵיהֶ֗ם אֲשֶׁ֣ר זִ֭בְּחוּ לַעֲצַבֵּ֣י כְנָ֑עַן וַתֶּחֱנַ֥ף הָ֝אָ֗רֶץ בַּדָּמִֽים׃ | 38 |
Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.
וַיִּטְמְא֥וּ בְמַעֲשֵׂיהֶ֑ם וַ֝יִּזְ֗נוּ בְּמַֽעַלְלֵיהֶֽם׃ | 39 |
Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
וַיִּֽחַר־אַ֣ף יְהוָ֣ה בְּעַמֹּ֑ו וַ֝יְתָעֵ֗ב אֶת־נַחֲלָתֹֽו׃ | 40 |
Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
וַיִּתְּנֵ֥ם בְּיַד־גֹּויִ֑ם וַֽיִּמְשְׁל֥וּ בָ֝הֶ֗ם שֹׂנְאֵיהֶֽם׃ | 41 |
Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
וַיִּלְחָצ֥וּם אֹויְבֵיהֶ֑ם וַ֝יִּכָּנְע֗וּ תַּ֣חַת יָדָֽם׃ | 42 |
Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
פְּעָמִ֥ים רַבֹּ֗ות יַצִּ֫ילֵ֥ם וְ֭הֵמָּה יַמְר֣וּ בַעֲצָתָ֑ם וַ֝יָּמֹ֗כּוּ בַּעֲוֹנָֽם׃ | 43 |
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
וַ֭יַּרְא בַּצַּ֣ר לָהֶ֑ם בְּ֝שָׁמְעֹ֗ו אֶת־רִנָּתָֽם׃ | 44 |
Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,
וַיִּזְכֹּ֣ר לָהֶ֣ם בְּרִיתֹ֑ו וַ֝יִּנָּחֵ֗ם כְּרֹ֣ב חַסְדֹּו (חֲסָדָֽיו)׃ | 45 |
ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
וַיִּתֵּ֣ן אֹותָ֣ם לְרַחֲמִ֑ים לִ֝פְנֵ֛י כָּל־שֹׁובֵיהֶֽם׃ | 46 |
Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú.
הֹושִׁיעֵ֨נוּ ׀ יְה֘וָ֤ה אֱלֹהֵ֗ינוּ וְקַבְּצֵנוּ֮ מִֽן־הַגֹּ֫ויִ֥ם לְ֭הֹדֹות לְשֵׁ֣ם קָדְשֶׁ֑ךָ לְ֝הִשְׁתַּבֵּ֗חַ בִּתְהִלָּתֶֽךָ׃ | 47 |
Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí, láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
בָּר֤וּךְ־יְהוָ֨ה אֱלֹהֵ֪י יִשְׂרָאֵ֡ל מִן־הָ֤עֹולָ֨ם ׀ וְעַ֬ד הָעֹולָ֗ם וְאָמַ֖ר כָּל־הָעָ֥ם אָמֵ֗ן הַֽלְלוּ־יָֽהּ׃ | 48 |
Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran. Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!” Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!