< מִשְׁלֵי 6 >
בְּ֭נִי אִם־עָרַ֣בְתָּ לְרֵעֶ֑ךָ תָּקַ֖עְתָּ לַזָּ֣ר כַּפֶּֽיךָ׃ | 1 |
Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn,
נֹוקַ֥שְׁתָּ בְאִמְרֵי־פִ֑יךָ נִ֝לְכַּ֗דְתָּ בְּאִמְרֵי־פִֽיךָ׃ | 2 |
bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté.
עֲשֵׂ֨ה זֹ֥את אֵפֹ֪וא ׀ בְּנִ֡י וְֽהִנָּצֵ֗ל כִּ֘י בָ֤אתָ בְכַף־רֵעֶ֑ךָ לֵ֥ךְ הִ֝תְרַפֵּ֗ס וּרְהַ֥ב רֵעֶֽיךָ׃ | 3 |
Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáradára.
אַל־תִּתֵּ֣ן שֵׁנָ֣ה לְעֵינֶ֑יךָ וּ֝תְנוּמָ֗ה לְעַפְעַפֶּֽיךָ׃ | 4 |
Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
הִ֭נָּצֵל כִּצְבִ֣י מִיָּ֑ד וּ֝כְצִפֹּ֗ור מִיַּ֥ד יָקֽוּשׁ׃ פ | 5 |
Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
לֵֽךְ־אֶל־נְמָלָ֥ה עָצֵ֑ל רְאֵ֖ה דְרָכֶ֣יהָ וַחֲכָֽם׃ | 6 |
Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
אֲשֶׁ֖ר אֵֽין־לָ֥הּ קָצִ֗ין שֹׁטֵ֥ר וּמֹשֵֽׁל׃ | 7 |
Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba,
תָּכִ֣ין בַּקַּ֣יִץ לַחְמָ֑הּ אָגְרָ֥ה בַ֝קָּצִ֗יר מַאֲכָלָֽהּ׃ | 8 |
síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.
עַד־מָתַ֖י עָצֵ֥ל ׀ תִּשְׁכָּ֑ב מָ֝תַ֗י תָּק֥וּם מִשְּׁנָתֶֽךָ׃ | 9 |
Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
מְעַ֣ט שֵׁ֭נֹות מְעַ֣ט תְּנוּמֹ֑ות מְעַ֓ט ׀ חִבֻּ֖ק יָדַ֣יִם לִשְׁכָּֽב׃ | 10 |
Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀.
וּבָֽא־כִמְהַלֵּ֥ךְ רֵאשֶׁ֑ךָ וּ֝מַחְסֹֽרְךָ֗ כְּאִ֣ישׁ מָגֵֽן׃ פ | 11 |
Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè.
אָדָ֣ם בְּ֭לִיַּעַל אִ֣ישׁ אָ֑וֶן הֹ֝ולֵ֗ךְ עִקְּשׁ֥וּת פֶּֽה׃ | 12 |
Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
קֹרֵ֣ץ בְּ֭עֵינָיו מֹלֵ֣ל בְּרַגְלָ֑ו מֹ֝רֶ֗ה בְּאֶצְבְּעֹתָֽיו׃ | 13 |
tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
תַּֽהְפֻּכֹ֨ות ׀ בְּלִבֹּ֗ו חֹרֵ֣שׁ רָ֣ע בְּכָל־עֵ֑ת מְדָנִים (מִדְיָנִ֥ים) יְשַׁלֵּֽחַ׃ | 14 |
tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
עַל־כֵּ֗ן פִּ֭תְאֹם יָבֹ֣וא אֵידֹ֑ו פֶּ֥תַע יִ֝שָּׁבֵ֗ר וְאֵ֣ין מַרְפֵּֽא׃ פ | 15 |
Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
שֶׁשׁ־הֵ֭נָּה שָׂנֵ֣א יְהוָ֑ה וְ֝שֶׁ֗בַע תֹּועֲבֹות (תֹּועֲבַ֥ת) נַפְשֹֽׁו׃ | 16 |
Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,
עֵינַ֣יִם רָ֭מֹות לְשֹׁ֣ון שָׁ֑קֶר וְ֝יָדַ֗יִם שֹׁפְכֹ֥ות דָּם־נָקִֽי׃ | 17 |
Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
לֵ֗ב חֹ֭רֵשׁ מַחְשְׁבֹ֣ות אָ֑וֶן רַגְלַ֥יִם מְ֝מַהֲרֹ֗ות לָר֥וּץ לָֽרָעָה׃ | 18 |
ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
יָפִ֣יחַ כְּ֭זָבִים עֵ֣ד שָׁ֑קֶר וּמְשַׁלֵּ֥חַ מְ֝דָנִ֗ים בֵּ֣ין אַחִֽים׃ פ | 19 |
ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.
נְצֹ֣ר בְּ֭נִי מִצְוַ֣ת אָבִ֑יךָ וְאַל־תִּ֝טֹּ֗שׁ תֹּורַ֥ת אִמֶּֽךָ׃ | 20 |
Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
קָשְׁרֵ֣ם עַל־לִבְּךָ֣ תָמִ֑יד עָ֝נְדֵ֗ם עַל־גַּרְגְּרֹתֶֽךָ׃ | 21 |
Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
בְּהִתְהַלֶּכְךָ֨ ׀ תַּנְחֶ֬ה אֹתָ֗ךְ בְּֽ֭שָׁכְבְּךָ תִּשְׁמֹ֣ר עָלֶ֑יךָ וַ֝הֲקִיצֹ֗ותָ הִ֣יא תְשִׂיחֶֽךָ׃ | 22 |
Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
כִּ֤י נֵ֣ר מִ֭צְוָה וְתֹ֣ורָה אֹ֑ור וְדֶ֥רֶךְ חַ֝יִּ֗ים תֹּוכְחֹ֥ות מוּסָֽר׃ | 23 |
Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè.
לִ֭שְׁמָרְךָ מֵאֵ֣שֶׁת רָ֑ע מֵֽ֝חֶלְקַ֗ת לָשֹׁ֥ון נָכְרִיָּֽה׃ | 24 |
Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.
אַל־תַּחְמֹ֣ד יָ֭פְיָהּ בִּלְבָבֶ֑ךָ וְאַל־תִּ֝קָּֽחֲךָ֗ בְּעַפְעַפֶּֽיהָ׃ | 25 |
Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.
כִּ֤י בְעַד־אִשָּׁ֥ה זֹונָ֗ה עַֽד־כִּכַּ֫ר לָ֥חֶם וְאֵ֥שֶׁת אִ֑ישׁ נֶ֖פֶשׁ יְקָרָ֣ה תָצֽוּד׃ פ | 26 |
Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan, ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
הֲיַחְתֶּ֤ה אִ֓ישׁ אֵ֬שׁ בְּחֵיקֹ֑ו וּ֝בְגָדָ֗יו לֹ֣א תִשָּׂרַֽפְנָה׃ | 27 |
Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?
אִם־יְהַלֵּ֣ךְ אִ֭ישׁ עַל־הַגֶּחָלִ֑ים וְ֝רַגְלָ֗יו לֹ֣א תִכָּוֶֽינָה׃ | 28 |
Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
כֵּ֗ן הַ֭בָּא אֶל־אֵ֣שֶׁת רֵעֵ֑הוּ לֹ֥א יִ֝נָּקֶ֗ה כָּֽל־הַנֹּגֵ֥עַ בָּֽהּ׃ | 29 |
Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.
לֹא־יָב֣וּזוּ לַ֭גַּנָּב כִּ֣י יִגְנֹ֑וב לְמַלֵּ֥א נַ֝פְשֹׁ֗ו כִּ֣י יִרְעָֽב׃ | 30 |
Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
וְ֭נִמְצָא יְשַׁלֵּ֣ם שִׁבְעָתָ֑יִם אֶת־כָּל־הֹ֖ון בֵּיתֹ֣ו יִתֵּֽן׃ | 31 |
Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
נֹאֵ֣ף אִשָּׁ֣ה חֲסַר־לֵ֑ב מַֽשְׁחִ֥ית נַ֝פְשֹׁ֗ו ה֣וּא יַעֲשֶֽׂנָּה׃ | 32 |
Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni.
נֶֽגַע־וְקָלֹ֥ון יִמְצָ֑א וְ֝חֶרְפָּתֹ֗ו לֹ֣א תִמָּחֶֽה׃ | 33 |
Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.
כִּֽי־קִנְאָ֥ה חֲמַת־גָּ֑בֶר וְלֹֽא־יַ֝חְמֹ֗ול בְּיֹ֣ום נָקָֽם׃ | 34 |
Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
לֹא־יִ֭שָּׂא פְּנֵ֣י כָל־כֹּ֑פֶר וְלֹֽא־יֹ֝אבֶ֗ה כִּ֣י תַרְבֶּה־שֹֽׁחַד׃ פ | 35 |
Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.