< אִיּוֹב 30 >
וְעַתָּ֤ה ׀ שָֽׂחֲק֣וּ עָלַי֮ צְעִירִ֥ים מִמֶּ֗נִּי לְיָ֫מִ֥ים אֲשֶׁר־מָאַ֥סְתִּי אֲבֹותָ֑ם לָ֝שִׁ֗ית עִם־כַּלְבֵ֥י צֹאנִֽי׃ | 1 |
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
גַּם־כֹּ֣חַ יְ֭דֵיהֶם לָ֣מָּה לִּ֑י עָ֝לֵ֗ימֹו אָ֣בַד כָּֽלַח׃ | 2 |
Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
בְּחֶ֥סֶר וּבְכָפָ֗ן גַּ֫לְמ֥וּד הַֽעֹרְקִ֥ים צִיָּ֑ה אֶ֝֗מֶשׁ שֹׁואָ֥ה וּמְשֹׁאָֽה׃ | 3 |
Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.
הַקֹּטְפִ֣ים מַלּ֣וּחַ עֲלֵי־שִׂ֑יחַ וְשֹׁ֖רֶשׁ רְתָמִ֣ים לַחְמָֽם׃ | 4 |
Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.
מִן־גֵּ֥ו יְגֹרָ֑שׁוּ יָרִ֥יעוּ עָ֝לֵ֗ימֹו כַּגַּנָּֽב׃ | 5 |
A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
בַּעֲר֣וּץ נְחָלִ֣ים לִשְׁכֹּ֑ן חֹרֵ֖י עָפָ֣ר וְכֵפִֽים׃ | 6 |
A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
בֵּין־שִׂיחִ֥ים יִנְהָ֑קוּ תַּ֖חַת חָר֣וּל יְסֻפָּֽחוּ׃ | 7 |
Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
בְּֽנֵי־נָ֭בָל גַּם־בְּנֵ֣י בְלִי־שֵׁ֑ם נִ֝כְּא֗וּ מִן־הָאָֽרֶץ׃ | 8 |
Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
וְ֭עַתָּה נְגִינָתָ֣ם הָיִ֑יתִי וָאֱהִ֖י לָהֶ֣ם לְמִלָּֽה׃ | 9 |
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
תִּֽ֭עֲבוּנִי רָ֣חֲקוּ מֶ֑נִּי וּ֝מִפָּנַ֗י לֹא־חָ֥שְׂכוּ רֹֽק׃ | 10 |
Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
כִּֽי־יִתְרֹו (יִתְרִ֣י) פִ֭תַּח וַיְעַנֵּ֑נִי וְ֝רֶ֗סֶן מִפָּנַ֥י שִׁלֵּֽחוּ׃ | 11 |
Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
עַל־יָמִין֮ פִּרְחַ֪ח יָ֫ק֥וּמוּ רַגְלַ֥י שִׁלֵּ֑חוּ וַיָּסֹ֥לּוּ עָ֝לַ֗י אָרְחֹ֥ות אֵידָֽם׃ | 12 |
Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
נָתְס֗וּ נְֽתִיבָ֫תִ֥י לְהַוָּתִֽי יֹעִ֑ילוּ לֹ֖א עֹזֵ֣ר לָֽמֹו׃ | 13 |
Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
כְּפֶ֣רֶץ רָחָ֣ב יֶאֱתָ֑יוּ תַּ֥חַת שֹׁ֝אָ֗ה הִתְגַּלְגָּֽלוּ׃ | 14 |
Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
הָהְפַּ֥ךְ עָלַ֗י בַּלָּ֫הֹ֥ות תִּרְדֹּ֣ף כָּ֭רוּחַ נְדִבָתִ֑י וּ֝כְעָ֗ב עָבְרָ֥ה יְשֻׁעָתִֽי׃ | 15 |
Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
וְעַתָּ֗ה עָ֭לַי תִּשְׁתַּפֵּ֣ךְ נַפְשִׁ֑י יֹ֖אחֲז֣וּנִי יְמֵי־עֹֽנִי׃ | 16 |
“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
לַ֗יְלָה עֲ֭צָמַי נִקַּ֣ר מֵעָלָ֑י וְ֝עֹרְקַ֗י לֹ֣א יִשְׁכָּבֽוּן׃ | 17 |
Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
בְּרָב־כֹּ֖חַ יִתְחַפֵּ֣שׂ לְבוּשִׁ֑י כְּפִ֖י כֻתָּנְתִּ֣י יַֽאַזְרֵֽנִי׃ | 18 |
Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.
הֹרָ֥נִי לַחֹ֑מֶר וָ֝אֶתְמַשֵּׁ֗ל כֶּעָפָ֥ר וָאֵֽפֶר׃ | 19 |
Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀, èmi sì dàbí eruku àti eérú.
אֲשַׁוַּ֣ע אֵ֭לֶיךָ וְלֹ֣א תַעֲנֵ֑נִי עָ֝מַ֗דְתִּי וַתִּתְבֹּ֥נֶן בִּֽי׃ | 20 |
“Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
תֵּהָפֵ֣ךְ לְאַכְזָ֣ר לִ֑י בְּעֹ֖צֶם יָדְךָ֣ תִשְׂטְמֵֽנִי׃ | 21 |
Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi; ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
תִּשָּׂאֵ֣נִי אֶל־ר֖וּחַ תַּרְכִּיבֵ֑נִי וּ֝תְמֹגְגֵ֗נִי תְּשֻׁוֶּה (תּוּשִׁיָּֽה)׃ | 22 |
Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
כִּֽי־יָ֭דַעְתִּי מָ֣וֶת תְּשִׁיבֵ֑נִי וּבֵ֖ית מֹועֵ֣ד לְכָל־חָֽי׃ | 23 |
Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
אַ֣ךְ לֹא־בְ֭עִי יִשְׁלַח־יָ֑ד אִם־בְּ֝פִידֹ֗ו לָהֶ֥ן שֽׁוּעַ׃ | 24 |
“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
אִם־לֹ֣א בָ֭כִיתִי לִקְשֵׁה־יֹ֑ום עָֽגְמָ֥ה נַ֝פְשִׁ֗י לָאֶבְיֹֽון׃ | 25 |
Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
כִּ֤י טֹ֣וב קִ֭וִּיתִי וַיָּ֣בֹא רָ֑ע וַֽאֲיַחֲלָ֥ה לְ֝אֹ֗ור וַיָּ֥בֹא אֹֽפֶל׃ | 26 |
Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
מֵעַ֖י רֻתְּח֥וּ וְלֹא־דָ֗מּוּ קִדְּמֻ֥נִי יְמֵי־עֹֽנִי׃ | 27 |
Ikùn mí n ru kò sì sinmi, ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
קֹדֵ֣ר הִ֭לַּכְתִּי בְּלֹ֣א חַמָּ֑ה קַ֖מְתִּי בַקָּהָ֣ל אֲשַׁוֵּֽעַ׃ | 28 |
Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
אָ֭ח הָיִ֣יתִי לְתַנִּ֑ים וְ֝רֵ֗עַ לִבְנֹ֥ות יַעֲנָֽה׃ | 29 |
Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
עֹ֖ורִי שָׁחַ֣ר מֵעָלָ֑י וְעַצְמִי־חָ֝֗רָה מִנִּי־חֹֽרֶב׃ | 30 |
Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi; egungun mi sì jórun fún ooru.
וַיְהִ֣י לְ֭אֵבֶל כִּנֹּרִ֑י וְ֝עֻגָבִ֗י לְקֹ֣ול בֹּכִֽים׃ | 31 |
Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀, àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.