< דברים 5 >

וַיִּקְרָא מֹשֶׁה אֶל־כׇּל־יִשְׂרָאֵל וַיֹּאמֶר אֲלֵהֶם שְׁמַע יִשְׂרָאֵל אֶת־הַחֻקִּים וְאֶת־הַמִּשְׁפָּטִים אֲשֶׁר אָנֹכִי דֹּבֵר בְּאׇזְנֵיכֶם הַיּוֹם וּלְמַדְתֶּם אֹתָם וּשְׁמַרְתֶּם לַעֲשֹׂתָֽם׃ 1
Mose sì pe gbogbo Israẹli jọ, ó sì wí pé, Gbọ́ ìwọ Israẹli, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etí ìgbọ́ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.
יְהֹוָה אֱלֹהֵינוּ כָּרַת עִמָּנוּ בְּרִית בְּחֹרֵֽב׃ 2
Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Horebu.
לֹא אֶת־אֲבֹתֵינוּ כָּרַת יְהֹוָה אֶת־הַבְּרִית הַזֹּאת כִּי אִתָּנוּ אֲנַחְנוּ אֵלֶּה פֹה הַיּוֹם כֻּלָּנוּ חַיִּֽים׃ 3
Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láààyè níbí lónìí.
פָּנִים ׀ בְּפָנִים דִּבֶּר יְהֹוָה עִמָּכֶם בָּהָר מִתּוֹךְ הָאֵֽשׁ׃ 4
Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrín iná lórí òkè.
אָנֹכִי עֹמֵד בֵּין־יְהֹוָה וּבֵֽינֵיכֶם בָּעֵת הַהִוא לְהַגִּיד לָכֶם אֶת־דְּבַר יְהֹוָה כִּי יְרֵאתֶם מִפְּנֵי הָאֵשׁ וְלֹֽא־עֲלִיתֶם בָּהָר לֵאמֹֽר׃ 5
(Ní ìgbà yìí, mo wà láàrín ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè.) Ó sì wí pé,
אָֽנֹכִי יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ אֲשֶׁר הוֹצֵאתִיךָ מֵאֶרֶץ מִצְרַיִם מִבֵּית עֲבָדִ͏ֽים׃ 6
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
לֹא־יִהְיֶ͏ֽה־לְךָ אֱלֹהִים אֲחֵרִים עַל־פָּנָֽ͏ַי׃ 7
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
לֹֽא־תַעֲשֶֽׂה־לְךָ פֶסֶל ׀ כׇּל־תְּמוּנָה אֲשֶׁר בַּשָּׁמַיִם ׀ מִמַּעַל וַאֲשֶׁר בָּאָרֶץ מִתָּ͏ַחַת וַאֲשֶׁר בַּמַּיִם ׀ מִתַּחַת לָאָֽרֶץ׃ 8
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
לֹא־תִשְׁתַּחֲוֶה לָהֶם וְלֹא תׇעׇבְדֵם כִּי אָנֹכִי יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ אֵל קַנָּא פֹּקֵד עֲוֺן אָבוֹת עַל־בָּנִים וְעַל־שִׁלֵּשִׁים וְעַל־רִבֵּעִים לְשֹׂנְאָֽי׃ 9
Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
וְעֹשֶׂה חֶסֶד לַֽאֲלָפִים לְאֹהֲבַי וּלְשֹׁמְרֵי (מצותו) [מִצְוֺתָֽי]׃ 10
Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
לֹא תִשָּׂא אֶת־שֵֽׁם־יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ לַשָּׁוְא כִּי לֹא יְנַקֶּה יְהֹוָה אֵת אֲשֶׁר־יִשָּׂא אֶת־שְׁמוֹ לַשָּֽׁוְא׃ 11
Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.
שָׁמוֹר אֶת־יוֹם הַשַּׁבָּת לְקַדְּשׁוֹ כַּאֲשֶׁר צִוְּךָ ׀ יְהֹוָה אֱלֹהֶֽיךָ׃ 12
Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.
שֵׁשֶׁת יָמִים תַּֽעֲבֹד וְעָשִׂיתָ כׇּֿל־מְלַאכְתֶּֽךָ׃ 13
Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ.
וְיוֹם הַשְּׁבִיעִי שַׁבָּת ׀ לַיהֹוָה אֱלֹהֶיךָ לֹא תַעֲשֶׂה כׇל־מְלָאכָה אַתָּה וּבִנְךָֽ־וּבִתֶּךָ וְעַבְדְּךָֽ־וַאֲמָתֶךָ וְשׁוֹרְךָ וַחֲמֹֽרְךָ וְכׇל־בְּהֶמְתֶּךָ וְגֵֽרְךָ אֲשֶׁר בִּשְׁעָרֶיךָ לְמַעַן יָנוּחַ עַבְדְּךָ וַאֲמָתְךָ כָּמֽוֹךָ׃ 14
Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti akọ màlúù rẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, àti ohun ọ̀sìn rẹ kan, àti àlejò tí ń bẹ nínú ibodè rẹ; kí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin kí ó lè sinmi gẹ́gẹ́ bí ìwọ.
וְזָכַרְתָּ כִּי־עֶבֶד הָיִיתָ ׀ בְּאֶרֶץ מִצְרַיִם וַיֹּצִאֲךָ יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ מִשָּׁם בְּיָד חֲזָקָה וּבִזְרֹעַ נְטוּיָה עַל־כֵּן צִוְּךָ יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ לַעֲשׂוֹת אֶת־יוֹם הַשַּׁבָּֽת׃ 15
Sì rántí pé, ìwọ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, àti pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yọ ọ́ kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe pàṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.
כַּבֵּד אֶת־אָבִיךָ וְאֶת־אִמֶּךָ כַּאֲשֶׁר צִוְּךָ יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ לְמַעַן ׀ יַאֲרִיכֻן יָמֶיךָ וּלְמַעַן יִיטַב לָךְ עַל הָֽאֲדָמָה אֲשֶׁר־יְהֹוָה אֱלֹהֶיךָ נֹתֵן לָֽךְ׃ 16
Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
לֹא תִּֿרְצָ͏ֽח׃ 17
Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.
וְלֹא תִּֿנְאָ͏ֽף׃ 18
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
וְלֹא תִּֿגְנֹֽב׃ 19
Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
וְלֹֽא־תַעֲנֶה בְרֵֽעֲךָ עֵד שָֽׁוְא׃ 20
Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
וְלֹא תַחְמֹד אֵשֶׁת רֵעֶךָ וְלֹא תִתְאַוֶּה בֵּית רֵעֶךָ שָׂדֵהוּ וְעַבְדּוֹ וַאֲמָתוֹ שׁוֹרוֹ וַחֲמֹרוֹ וְכֹל אֲשֶׁר לְרֵעֶֽךָ׃ 21
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéji rẹ, oko rẹ̀, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéji rẹ.”
אֶֽת־הַדְּבָרִים הָאֵלֶּה דִּבֶּר יְהֹוָה אֶל־כׇּל־קְהַלְכֶם בָּהָר מִתּוֹךְ הָאֵשׁ הֶֽעָנָן וְהָֽעֲרָפֶל קוֹל גָּדוֹל וְלֹא יָסָף וַֽיִּכְתְּבֵם עַל־שְׁנֵי לֻחֹת אֲבָנִים וַֽיִּתְּנֵם אֵלָֽי׃ 22
Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrín iná, ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú wàláà méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.
וַיְהִי כְּשׇׁמְעֲכֶם אֶת־הַקּוֹל מִתּוֹךְ הַחֹשֶׁךְ וְהָהָר בֹּעֵר בָּאֵשׁ וַתִּקְרְבוּן אֵלַי כׇּל־רָאשֵׁי שִׁבְטֵיכֶם וְזִקְנֵיכֶֽם׃ 23
Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọ iná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn àgbàgbà yín tọ̀ mí wá.
וַתֹּאמְרוּ הֵן הֶרְאָנוּ יְהֹוָה אֱלֹהֵינוּ אֶת־כְּבֹדוֹ וְאֶת־גׇּדְלוֹ וְאֶת־קֹלוֹ שָׁמַעְנוּ מִתּוֹךְ הָאֵשׁ הַיּוֹם הַזֶּה רָאִינוּ כִּֽי־יְדַבֵּר אֱלֹהִים אֶת־הָֽאָדָם וָחָֽי׃ 24
Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárín iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láààyè lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá bá a sọ̀rọ̀.
וְעַתָּה לָמָּה נָמוּת כִּי תֹֽאכְלֵנוּ הָאֵשׁ הַגְּדֹלָה הַזֹּאת אִם־יֹסְפִים ׀ אֲנַחְנוּ לִשְׁמֹעַ אֶת־קוֹל יְהֹוָה אֱלֹהֵינוּ עוֹד וָמָֽתְנוּ׃ 25
Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.
כִּי מִי כׇל־בָּשָׂר אֲשֶׁר שָׁמַע קוֹל אֱלֹהִים חַיִּים מְדַבֵּר מִתּוֹךְ־הָאֵשׁ כָּמֹנוּ וַיֶּֽחִי׃ 26
Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Ọlọ́run alààyè láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?
קְרַב אַתָּה וּֽשְׁמָע אֵת כׇּל־אֲשֶׁר יֹאמַר יְהֹוָה אֱלֹהֵינוּ וְאַתְּ ׀ תְּדַבֵּר אֵלֵינוּ אֵת כׇּל־אֲשֶׁר יְדַבֵּר יְהֹוָה אֱלֹהֵינוּ אֵלֶיךָ וְשָׁמַעְנוּ וְעָשִֽׂינוּ׃ 27
Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́rọ̀.”
וַיִּשְׁמַע יְהֹוָה אֶת־קוֹל דִּבְרֵיכֶם בְּדַבֶּרְכֶם אֵלָי וַיֹּאמֶר יְהֹוָה אֵלַי שָׁמַעְתִּי אֶת־קוֹל דִּבְרֵי הָעָם הַזֶּה אֲשֶׁר דִּבְּרוּ אֵלֶיךָ הֵיטִיבוּ כׇּל־אֲשֶׁר דִּבֵּֽרוּ׃ 28
Olúwa ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,
מִֽי־יִתֵּן וְהָיָה לְבָבָם זֶה לָהֶם לְיִרְאָה אֹתִי וְלִשְׁמֹר אֶת־כׇּל־מִצְוֺתַי כׇּל־הַיָּמִים לְמַעַן יִיטַב לָהֶם וְלִבְנֵיהֶם לְעֹלָֽם׃ 29
ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.
לֵךְ אֱמֹר לָהֶם שׁוּבוּ לָכֶם לְאׇהֳלֵיכֶֽם׃ 30
“Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn.
וְאַתָּה פֹּה עֲמֹד עִמָּדִי וַאֲדַבְּרָה אֵלֶיךָ אֵת כׇּל־הַמִּצְוָה וְהַחֻקִּים וְהַמִּשְׁפָּטִים אֲשֶׁר תְּלַמְּדֵם וְעָשׂוּ בָאָרֶץ אֲשֶׁר אָנֹכִי נֹתֵן לָהֶם לְרִשְׁתָּֽהּ׃ 31
Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àṣẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”
וּשְׁמַרְתֶּם לַעֲשׂוֹת כַּאֲשֶׁר צִוָּה יְהֹוָה אֱלֹהֵיכֶם אֶתְכֶם לֹא תָסֻרוּ יָמִין וּשְׂמֹֽאל׃ 32
Torí èyí, ẹ ṣọ́ra láti máa ṣe ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì.
בְּכׇל־הַדֶּרֶךְ אֲשֶׁר צִוָּה יְהֹוָה אֱלֹהֵיכֶם אֶתְכֶם תֵּלֵכוּ לְמַעַן תִּֽחְיוּן וְטוֹב לָכֶם וְהַאֲרַכְתֶּם יָמִים בָּאָרֶץ אֲשֶׁר תִּֽירָשֽׁוּן׃ 33
Ẹ rìn ní gbogbo ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ bá à le yè, kí ó sì dára fún un yín, kí ọjọ́ ọ yín bá à lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà.

< דברים 5 >