< תהילים 89 >

משכיל לאיתן האזרחי ב חסדי יהוה עולם אשירה לדר ודר אודיע אמונתך בפי 1
Maskili ti Etani ará Esra. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
כי-אמרתי--עולם חסד יבנה שמים תכן אמונתך בהם 2
Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé, pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.
כרתי ברית לבחירי נשבעתי לדוד עבדי 3
Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
עד-עולם אכין זרעך ובניתי לדר-ודור כסאך סלה 4
‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’”
ויודו שמים פלאך יהוה אף-אמונתך בקהל קדשים 5
Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
כי מי בשחק יערך ליהוה ידמה ליהוה בבני אלים 6
Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
אל נערץ בסוד-קדשים רבה ונורא על-כל-סביביו 7
Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
יהוה אלהי צבאות--מי-כמוך חסין יה ואמונתך סביבותיך 8
Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
אתה מושל בגאות הים בשוא גליו אתה תשבחם 9
Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
אתה דכאת כחלל רהב בזרוע עזך פזרת אויביך 10
Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa; ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
לך שמים אף-לך ארץ תבל ומלאה אתה יסדתם 11
Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ: ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
צפון וימין אתה בראתם תבור וחרמון בשמך ירננו 12
Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
לך זרוע עם-גבורה תעז ידך תרום ימינך 13
Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
צדק ומשפט מכון כסאך חסד ואמת יקדמו פניך 14
Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ: ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
אשרי העם ידעי תרועה יהוה באור-פניך יהלכון 15
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
בשמך יגילון כל-היום ובצדקתך ירומו 16
Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ.
כי-תפארת עזמו אתה וברצונך תרים (תרום) קרנינו 17
Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
כי ליהוה מגננו ולקדוש ישראל מלכנו 18
Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
אז דברת בחזון לחסידיך-- ותאמר שויתי עזר על-גבור הרימותי בחור מעם 19
Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
מצאתי דוד עבדי בשמן קדשי משחתיו 20
Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.
אשר ידי תכון עמו אף-זרועי תאמצנו 21
Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.
לא-ישיא אויב בו ובן-עולה לא יעננו 22
Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
וכתותי מפניו צריו ומשנאיו אגוף 23
Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.
ואמונתי וחסדי עמו ובשמי תרום קרנו 24
Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
ושמתי בים ידו ובנהרות ימינו 25
Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun, àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.
הוא יקראני אבי אתה אלי וצור ישועתי 26
Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
אף-אני בכור אתנהו עליון למלכי-ארץ 27
Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi, ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
לעולם אשמור- (אשמר-) לו חסדי ובריתי נאמנת לו 28
Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
ושמתי לעד זרעו וכסאו כימי שמים 29
Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé, àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
אם-יעזבו בניו תורתי ובמשפטי לא ילכון 30
“Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
אם-חקתי יחללו ומצותי לא ישמרו 31
Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́ tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
ופקדתי בשבט פשעם ובנגעים עונם 32
nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò; àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;
וחסדי לא-אפיר מעמו ולא-אשקר באמונתי 33
ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
לא-אחלל בריתי ומוצא שפתי לא אשנה 34
Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
אחת נשבעתי בקדשי אם-לדוד אכזב 35
Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
זרעו לעולם יהיה וכסאו כשמש נגדי 36
Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
כירח יכון עולם ועד בשחק נאמן סלה 37
A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá, àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” (Sela)
ואתה זנחת ותמאס התעברת עם-משיחך 38
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.
נארתה ברית עבדך חללת לארץ נזרו 39
Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo; ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.
פרצת כל-גדרתיו שמת מבצריו מחתה 40
Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
שסהו כל-עברי דרך היה חרפה לשכניו 41
Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ; ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
הרימות ימין צריו השמחת כל-אויביו 42
Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè; ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
אף-תשיב צור חרבו ולא הקימתו במלחמה 43
Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà, ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
השבת מטהרו וכסאו לארץ מגרתה 44
Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà, ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
הקצרת ימי עלומיו העטית עליו בושה סלה 45
Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú; ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.
עד-מה יהוה תסתר לנצח תבער כמו-אש חמתך 46
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé? Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
זכר-אני מה-חלד על-מה-שוא בראת כל-בני-אדם 47
Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
מי גבר יחיה ולא יראה-מות ימלט נפשו מיד-שאול סלה (Sheol h7585) 48
Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀? Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú? (Sheol h7585)
איה חסדיך הראשנים אדני נשבעת לדוד באמונתך 49
Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà, tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
זכר אדני חרפת עבדיך שאתי בחיקי כל-רבים עמים 50
Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ; bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
אשר חרפו אויביך יהוה אשר חרפו עקבות משיחך 51
ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa, tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
ברוך יהוה לעולם אמן ואמן 52
Olùbùkún ní Olúwa títí láé.

< תהילים 89 >