< תהילים 87 >

לבני-קרח מזמור שיר יסודתו בהררי-קדש 1
Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
אהב יהוה שערי ציון-- מכל משכנות יעקב 2
Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
נכבדות מדבר בך-- עיר האלהים סלה 3
Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,
אזכיר רהב ובבל-- לידעי הנה פלשת וצר עם-כוש זה ילד-שם 4
“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’”
ולציון יאמר-- איש ואיש ילד-בה והוא יכוננה עליון 5
Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
יהוה--יספר בכתוב עמים זה ילד-שם סלה 6
Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
ושרים כחללים-- כל-מעיני בך 7
Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

< תהילים 87 >