< תהילים 68 >
למנצח לדוד מזמור שיר ב יקום אלהים יפוצו אויביו וינוסו משנאיו מפניו | 1 |
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin. Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká; kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
כהנדף עשן תנדף כהמס דונג מפני-אש-- יאבדו רשעים מפני אלהים | 2 |
Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ, kí ó fẹ́ wọn lọ; bí ìda ti í yọ́ níwájú iná, kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
וצדיקים--ישמחו יעלצו לפני אלהים וישישו בשמחה | 3 |
Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run; kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
שירו לאלהים-- זמרו שמו סלו לרכב בערבות--ביה שמו ועלזו לפניו | 4 |
Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù. Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
אבי יתומים ודין אלמנות-- אלהים במעון קדשו | 5 |
Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́
אלהים מושיב יחידים ביתה-- מוציא אסירים בכושרות אך סוררים שכנו צחיחה | 6 |
Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
אלהים--בצאתך לפני עמך בצעדך בישימון סלה | 7 |
Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, (Sela)
ארץ רעשה אף-שמים נטפו-- מפני אלהים זה סיני-- מפני אלהים אלהי ישראל | 8 |
Ilẹ̀ mì títí, àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde, níwájú Ọlọ́run, ẹni Sinai, níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
גשם נדבות תניף אלהים נחלתך ונלאה אתה כוננתה | 9 |
Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run; ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
חיתך ישבו-בה תכין בטובתך לעני אלהים | 10 |
Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
אדני יתן-אמר המבשרות צבא רב | 11 |
Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
מלכי צבאות ידדון ידדון ונות-בית תחלק שלל | 12 |
“Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ; obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
אם-תשכבון בין שפתים כנפי יונה נחפה בכסף ואברותיה בירקרק חרוץ | 13 |
Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran, nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà, àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
בפרש שדי מלכים בה-- תשלג בצלמון | 14 |
Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
הר-אלהים הר-בשן הר גבננים הר-בשן | 15 |
Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
למה תרצדון-- הרים גבננים ההר--חמד אלהים לשבתו אף-יהוה ישכן לנצח | 16 |
Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
רכב אלהים רבתים אלפי שנאן אדני בם סיני בקדש | 17 |
Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
עלית למרום שבית שבי-- לקחת מתנות באדם ואף סוררים לשכן יה אלהים | 18 |
Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
ברוך אדני יום יום יעמס-לנו--האל ישועתנו סלה | 19 |
Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. (Sela)
האל לנו אל למושעות וליהוה אדני--למות תצאות | 20 |
Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
אך-אלהים--ימחץ ראש איביו קדקד שער--מתהלך באשמיו | 21 |
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
אמר אדני מבשן אשיב אשיב ממצלות ים | 22 |
Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani; èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
למען תמחץ רגלך--בדם לשון כלביך--מאיבים מנהו | 23 |
kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ, àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
ראו הליכותיך אלהים הליכות אלי מלכי בקדש | 24 |
Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run, ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
קדמו שרים אחר נגנים בתוך עלמות תופפות | 25 |
Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn; àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.
במקהלות ברכו אלהים אדני ממקור ישראל | 26 |
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
שם בנימן צעיר רדם--שרי יהודה רגמתם שרי זבלון שרי נפתלי | 27 |
Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
צוה אלהיך עזך עוזה אלהים--זו פעלת לנו | 28 |
Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run; fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
מהיכלך על-ירושלם-- לך יובילו מלכים שי | 29 |
Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
גער חית קנה עדת אבירים בעגלי עמים-- מתרפס ברצי-כסף בזר עמים קרבות יחפצו | 30 |
Bá àwọn ẹranko búburú wí, tí ń gbé láàrín eèsún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà: tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.
יאתיו חשמנים מני מצרים כוש תריץ ידיו לאלהים | 31 |
Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti; Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
ממלכות הארץ שירו לאלהים זמרו אדני סלה | 32 |
Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé, kọrin ìyìn sí Olúwa, (Sela)
לרכב בשמי שמי-קדם-- הן יתן בקולו קול עז | 33 |
Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè, tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
תנו עז לאלהים על-ישראל גאותו ועזו בשחקים | 34 |
Kéde agbára Ọlọ́run, ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli, tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
נורא אלהים ממקדשיך אל ישראל-- הוא נתן עז ותעצמות לעם ברוך אלהים | 35 |
Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ; Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ. Olùbùkún ní Ọlọ́run!