< תהילים 50 >
מזמור לאסף אל אלהים יהוה-- דבר ויקרא-ארץ ממזרח-שמש עד-מבאו | 1 |
Saamu ti Asafu. Olúwa, Ọlọ́run alágbára, sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
מציון מכלל-יפי-- אלהים הופיע | 2 |
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà, Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
יבא אלהינו ואל-יחרש אש-לפניו תאכל וסביביו נשערה מאד | 3 |
Ọlọ́run ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́, iná yóò máa jó níwájú rẹ̀, àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
יקרא אל-השמים מעל ואל-הארץ לדין עמו | 4 |
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé, kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
אספו-לי חסידי-- כרתי בריתי עלי-זבח | 5 |
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
ויגידו שמים צדקו כי-אלהים שפט הוא סלה | 6 |
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀, nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́.
שמעה עמי ואדברה-- ישראל ואעידה בך אלהים אלהיך אנכי | 7 |
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ: èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
לא על-זבחיך אוכיחך ועולתיך לנגדי תמיד | 8 |
Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ rẹ, tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo.
לא-אקח מביתך פר ממכלאתיך עתודים | 9 |
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀
כי-לי כל-חיתו-יער בהמות בהררי-אלף | 10 |
nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
ידעתי כל-עוף הרים וזיז שדי עמדי | 11 |
Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.
אם-ארעב לא-אמר לך כי-לי תבל ומלאה | 12 |
Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú rẹ̀.
האוכל בשר אבירים ודם עתודים אשתה | 13 |
Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?
זבח לאלהים תודה ושלם לעליון נדריך | 14 |
“Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run, kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
וקראני ביום צרה אחלצך ותכבדני | 15 |
Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
ולרשע אמר אלהים מה-לך לספר חקי ותשא בריתי עלי-פיך | 16 |
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ, tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
ואתה שנאת מוסר ותשלך דברי אחריך | 17 |
Ìwọ kórìíra àṣẹ mi, ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
אם-ראית גנב ותרץ עמו ועם מנאפים חלקך | 18 |
Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn, ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
פיך שלחת ברעה ולשונך תצמיד מרמה | 19 |
Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú, ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
תשב באחיך תדבר בבן-אמך תתן-דפי | 20 |
Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ, ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
אלה עשית והחרשתי-- דמית היות-אהיה כמוך אוכיחך ואערכה לעיניך | 21 |
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́; ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí, èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
בינו-נא זאת שכחי אלוה פן-אטרף ואין מציל | 22 |
“Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
זבח תודה יכבדנני ושם דרך--אראנו בישע אלהים | 23 |
Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”