< תהילים 41 >
למנצח מזמור לדוד ב אשרי משכיל אל-דל ביום רעה ימלטהו יהוה | 1 |
Fún adarí orin. Saamu Dafidi. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
יהוה ישמרהו ויחיהו--יאשר (ואשר) בארץ ואל-תתנהו בנפש איביו | 2 |
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
יהוה--יסעדנו על-ערש דוי כל-משכבו הפכת בחליו | 3 |
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
אני-אמרתי יהוה חנני רפאה נפשי כי-חטאתי לך | 4 |
Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
אויבי--יאמרו רע לי מתי ימות ואבד שמו | 5 |
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé, “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
ואם-בא לראות שוא ידבר--לבו יקבץ-און לו יצא לחוץ ידבר | 6 |
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
יחד--עלי יתלחשו כל-שנאי עלי--יחשבו רעה לי | 7 |
Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
דבר-בליעל יצוק בו ואשר שכב לא-יוסיף לקום | 8 |
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.”
גם-איש שלומי אשר-בטחתי בו-- אוכל לחמי הגדיל עלי עקב | 9 |
Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
ואתה יהוה חנני והקימני ואשלמה להם | 10 |
Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi; gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
בזאת ידעתי כי-חפצת בי כי לא-יריע איבי עלי | 11 |
Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi, nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
ואני--בתמי תמכת בי ותציבני לפניך לעולם | 12 |
Bí ó ṣe tèmi ni ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
ברוך יהוה אלהי ישראל--מהעולם ועד העולם אמן ואמן | 13 |
Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé.