< תהילים 147 >
הללו-יה כי-טוב זמרה אלהינו-- כי-נעים נאוה תהלה | 1 |
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa, ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
בונה ירושלם יהוה נדחי ישראל יכנס | 2 |
Olúwa kọ́ Jerusalẹmu; Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
הרפא לשבורי לב ומחבש לעצבותם | 3 |
Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
מונה מספר לכוכבים לכלם שמות יקרא | 4 |
Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.
גדול אדונינו ורב-כח לתבונתו אין מספר | 5 |
Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
מעודד ענוים יהוה משפיל רשעים עדי-ארץ | 6 |
Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
ענו ליהוה בתודה זמרו לאלהינו בכנור | 7 |
Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
המכסה שמים בעבים-- המכין לארץ מטר המצמיח הרים חציר | 8 |
Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀ ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
נותן לבהמה לחמה לבני ערב אשר יקראו | 9 |
Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
לא בגבורת הסוס יחפץ לא-בשוקי האיש ירצה | 10 |
Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin, bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
רוצה יהוה את-יראיו-- את-המיחלים לחסדו | 11 |
Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
שבחי ירושלם את-יהוה הללי אלהיך ציון | 12 |
Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu; yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
כי-חזק בריחי שעריך ברך בניך בקרבך | 13 |
Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára, Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
השם-גבולך שלום חלב חטים ישביעך | 14 |
Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
השלח אמרתו ארץ עד-מהרה ירוץ דברו | 15 |
Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
הנתן שלג כצמר כפור כאפר יפזר | 16 |
Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
משליך קרחו כפתים לפני קרתו מי יעמד | 17 |
Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
ישלח דברו וימסם ישב רוחו יזלו-מים | 18 |
Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́ ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
מגיד דברו ליעקב חקיו ומשפטיו לישראל | 19 |
Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.
לא עשה כן לכל-גוי-- ומשפטים בל-ידעום הללו-יה | 20 |
Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀ wọn ko mọ òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.