< תהילים 141 >

מזמור לדוד יהוה קראתיך חושה לי האזינה קולי בקראי-לך 1
Saamu ti Dafidi. Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
תכון תפלתי קטרת לפניך משאת כפי מנחת-ערב 2
Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
שיתה יהוה שמרה לפי נצרה על-דל שפתי 3
Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
אל-תט-לבי לדבר רע להתעולל עללות ברשע-- את-אישים פעלי-און ובל-אלחם במנעמיהם 4
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
יהלמני צדיק חסד ויוכיחני-- שמן ראש אל-יני ראשי כי-עוד ותפלתי ברעותיהם 5
Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mi ní orí. Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.
נשמטו בידי-סלע שפטיהם ושמעו אמרי כי נעמו 6
A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta, àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
כמו פלח ובקע בארץ-- נפזרו עצמינו לפי שאול (Sheol h7585) 7
Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.” (Sheol h7585)
כי אליך יהוה אדני עיני בכה חסיתי אל-תער נפשי 8
Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè; nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
שמרני--מידי פח יקשו לי ומקשות פעלי און 9
Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi, kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
יפלו במכמריו רשעים יחד אנכי עד-אעבור 10
Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

< תהילים 141 >