< תהילים 108 >
שיר מזמור לדוד נכון לבי אלהים אשירה ואזמרה אף-כבודי | 1 |
Orin. Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.
עורה הנבל וכנור אעירה שחר | 2 |
Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù,
אודך בעמים יהוה ואזמרך בלאמים | 3 |
èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.
כי-גדול מעל-שמים חסדך ועד-שחקים אמתך | 4 |
Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.
רומה על-שמים אלהים ועל כל-הארץ כבודך | 5 |
Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
למען יחלצון ידידיך הושיעה ימינך וענני | 6 |
Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn
אלהים דבר בקדשו--אעלזה אחלקה שכם ועמק סכות אמדד | 7 |
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.
לי גלעד לי מנשה ואפרים מעוז ראשי יהודה מחקקי | 8 |
Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi,
מואב סיר רחצי--על-אדום אשליך נעלי עלי-פלשת אתרועע | 9 |
Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
מי יבלני עיר מבצר מי נחני עד-אדום | 10 |
Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
הלא-אלהים זנחתנו ולא-תצא אלהים בצבאתינו | 11 |
Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀. Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
הבה-לנו עזרת מצר ושוא תשועת אדם | 12 |
Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
באלהים נעשה-חיל והוא יבוס צרינו | 13 |
Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.