< מִשְׁלֵי 1 >
משלי שלמה בן-דוד-- מלך ישראל | 1 |
Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.
לדעת חכמה ומוסר להבין אמרי בינה | 2 |
Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
לקחת מוסר השכל צדק ומשפט ומשרים | 3 |
Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
לתת לפתאים ערמה לנער דעת ומזמה | 4 |
láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
ישמע חכם ויוסף לקח ונבון תחבלות יקנה | 5 |
Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
להבין משל ומליצה דברי חכמים וחידתם | 6 |
Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.
יראת יהוה ראשית דעת חכמה ומוסר אוילים בזו | 7 |
Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
שמע בני מוסר אביך ואל-תטש תורת אמך | 8 |
Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
כי לוית חן הם לראשך וענקים לגרגרתך | 9 |
Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
בני-- אם-יפתוך חטאים אל-תבא | 10 |
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
אם-יאמרו לכה אתנו נארבה לדם נצפנה לנקי חנם | 11 |
Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
נבלעם כשאול חיים ותמימים כיורדי בור (Sheol ) | 12 |
jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; (Sheol )
כל-הון יקר נמצא נמלא בתינו שלל | 13 |
a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,
גורלך תפיל בתוכנו כיס אחד יהיה לכלנו | 14 |
da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”
בני--אל-תלך בדרך אתם מנע רגלך מנתיבתם | 15 |
ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.
כי רגליהם לרע ירוצו וימהרו לשפך-דם | 16 |
Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
כי-חנם מזרה הרשת-- בעיני כל-בעל כנף | 17 |
Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ!
והם לדמם יארבו יצפנו לנפשתם | 18 |
Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn. Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà.
כן--ארחות כל-בצע בצע את-נפש בעליו יקח | 19 |
Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.
חכמות בחוץ תרנה ברחבות תתן קולה | 20 |
Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;
בראש המיות תקרא בפתחי שערים בעיר--אמריה תאמר | 21 |
láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:
עד-מתי פתים-- תאהבו-פתי ולצים--לצון חמדו להם וכסילים ישנאו-דעת | 22 |
“Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
תשובו לתוכחתי הנה אביעה לכם רוחי אודיעה דברי אתכם | 23 |
Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.
יען קראתי ותמאנו נטיתי ידי ואין מקשיב | 24 |
Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,
ותפרעו כל-עצתי ותוכחתי לא אביתם | 25 |
níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,
גם-אני באידכם אשחק אלעג בבא פחדכם | 26 |
Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.
בבא כשאוה (כשואה) פחדכם-- ואידכם כסופה יאתה בבא עליכם צרה וצוקה | 27 |
Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.
אז יקראנני ולא אענה ישחרנני ולא ימצאנני | 28 |
“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
תחת כי-שנאו דעת ויראת יהוה לא בחרו | 29 |
Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.
לא-אבו לעצתי נאצו כל-תוכחתי | 30 |
Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
ויאכלו מפרי דרכם וממעצתיהם ישבעו | 31 |
wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.
כי משובת פתים תהרגם ושלות כסילים תאבדם | 32 |
Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
ושמע לי ישכן-בטח ושאנן מפחד רעה | 33 |
ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”