< מִשְׁלֵי 24 >
אל-תקנא באנשי רעה ואל-תתאו להיות אתם | 1 |
Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
כי-שד יהגה לבם ועמל שפתיהם תדברנה | 2 |
nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
בחכמה יבנה בית ובתבונה יתכונן | 3 |
Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
ובדעת חדרים ימלאו-- כל-הון יקר ונעים | 4 |
nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
גבר-חכם בעוז ואיש-דעת מאמץ-כח | 5 |
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.
כי בתחבלות תעשה-לך מלחמה ותשועה ברב יועץ | 6 |
Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
ראמות לאויל חכמות בשער לא יפתח-פיהו | 7 |
Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
מחשב להרע-- לו בעל-מזמות יקראו | 8 |
Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
זמת אולת חטאת ותועבת לאדם לץ | 9 |
Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
התרפית ביום צרה-- צר כחכה | 10 |
Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
הצל לקחים למות ומטים להרג אם-תחשוך | 11 |
Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
כי-תאמר-- הן לא-ידענו-זה הלא-תכן לבות הוא-יבין ונצר נפשך הוא ידע והשיב לאדם כפעלו | 12 |
Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
אכל-בני דבש כי-טוב ונפת מתוק על-חכך | 13 |
Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
כן דעה חכמה--לנפשך אם-מצאת ויש אחרית ותקותך לא תכרת | 14 |
Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.
אל-תארב רשע לנוה צדיק אל-תשדד רבצו | 15 |
Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú láti gba ibùjókòó olódodo, má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
כי שבע יפול צדיק וקם ורשעים יכשלו ברעה | 16 |
nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni, ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.
בנפל אויביך (אויבך) אל-תשמח ובכשלו אל-יגל לבך | 17 |
Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú; nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
פן-יראה יהוה ורע בעיניו והשיב מעליו אפו | 18 |
Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
אל-תתחר במרעים אל-תקנא ברשעים | 19 |
Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
כי לא-תהיה אחרית לרע נר רשעים ידעך | 20 |
nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
ירא-את-יהוה בני ומלך עם-שונים אל-תתערב | 21 |
Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
כי-פתאם יקום אידם ופיד שניהם מי יודע | 22 |
Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
גם-אלה לחכמים הכר-פנים במשפט בל-טוב | 23 |
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n: láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
אמר לרשע--צדיק אתה יקבהו עמים יזעמוהו לאמים | 24 |
Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
ולמוכיחים ינעם ועליהם תבוא ברכת-טוב | 25 |
Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
שפתים ישק משיב דברים נכחים | 26 |
Ìdáhùn òtítọ́ dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.
הכן בחוץ מלאכתך--ועתדה בשדה לך אחר ובנית ביתך | 27 |
Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
אל-תהי עד-חנם ברעך והפתית בשפתיך | 28 |
Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
אל-תאמר--כאשר עשה-לי כן אעשה-לו אשיב לאיש כפעלו | 29 |
Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
על-שדה איש-עצל עברתי ועל-כרם אדם חסר-לב | 30 |
Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
והנה עלה כלו קמשנים--כסו פניו חרלים וגדר אבניו נהרסה | 31 |
ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà.
ואחזה אנכי אשית לבי ראיתי לקחתי מוסר | 32 |
Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
מעט שנות מעט תנומות מעט חבק ידים לשכב | 33 |
oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
ובא-מתהלך רישך ומחסריך כאיש מגן | 34 |
òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.