< מִשְׁלֵי 14 >

חכמות נשים בנתה ביתה ואולת בידיה תהרסנו 1
Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
הולך בישרו ירא יהוה ונלוז דרכיו בוזהו 2
Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.
בפי-אויל חטר גאוה ושפתי חכמים תשמורם 3
Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
באין אלפים אבוס בר ורב-תבואות בכח שור 4
Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní, ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
עד אמונים לא יכזב ויפיח כזבים עד שקר 5
Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
בקש-לץ חכמה ואין ודעת לנבון נקל 6
Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
לך מנגד לאיש כסיל ובל-ידעת שפתי-דעת 7
Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
חכמת ערום הבין דרכו ואולת כסילים מרמה 8
Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
אולים יליץ אשם ובין ישרים רצון 9
Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.
לב--יודע מרת נפשו ובשמחתו לא-יתערב זר 10
Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
בית רשעים ישמד ואהל ישרים יפריח 11
A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.
יש דרך ישר לפני-איש ואחריתה דרכי-מות 12
Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
גם-בשחק יכאב-לב ואחריתה שמחה תוגה 13
Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.
מדרכיו ישבע סוג לב ומעליו איש טוב 14
A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
פתי יאמין לכל-דבר וערום יבין לאשרו 15
Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
חכם ירא וסר מרע וכסיל מתעבר ובוטח 16
Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
קצר-אפים יעשה אולת ואיש מזמות ישנא 17
Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn.
נחלו פתאים אולת וערומים יכתרו דעת 18
Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.
שחו רעים לפני טובים ורשעים על-שערי צדיק 19
Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
גם-לרעהו ישנא רש ואהבי עשיר רבים 20
Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
בז-לרעהו חוטא ומחונן עניים (ענוים) אשריו 21
Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.
הלוא-יתעו חרשי רע וחסד ואמת חרשי טוב 22
Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí? Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.
בכל-עצב יהיה מותר ודבר-שפתים אך-למחסור 23
Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
עטרת חכמים עשרם אולת כסילים אולת 24
Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.
מציל נפשות עד אמת ויפח כזבים מרמה 25
Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.
ביראת יהוה מבטח-עז ולבניו יהיה מחסה 26
Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
יראת יהוה מקור חיים-- לסור ממקשי מות 27
Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
ברב-עם הדרת-מלך ובאפס לאם מחתת רזון 28
Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba, ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.
ארך אפים רב-תבונה וקצר-רוח מרים אולת 29
Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
חיי בשרים לב מרפא ורקב עצמות קנאה 30
Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
עשק דל חרף עשהו ומכבדו חנן אביון 31
Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
ברעתו ידחה רשע וחסה במותו צדיק 32
Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
בלב נבון תנוח חכמה ובקרב כסילים תודע 33
Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
צדקה תרומם-גוי וחסד לאמים חטאת 34
Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
רצון-מלך לעבד משכיל ועברתו תהיה מביש 35
Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.

< מִשְׁלֵי 14 >