< מִשְׁלֵי 11 >
מאזני מרמה תועבת יהוה ואבן שלמה רצונו | 1 |
Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
בא-זדון ויבא קלון ואת-צנועים חכמה | 2 |
Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
תמת ישרים תנחם וסלף בגדים ושדם (ישדם) | 3 |
Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.
לא-יועיל הון ביום עברה וצדקה תציל ממות | 4 |
Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
צדקת תמים תישר דרכו וברשעתו יפל רשע | 5 |
Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn, ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.
צדקת ישרים תצילם ובהות בגדים ילכדו | 6 |
Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.
במות אדם רשע תאבד תקוה ותוחלת אונים אבדה | 7 |
Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun; gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.
צדיק מצרה נחלץ ויבא רשע תחתיו | 8 |
A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.
בפה--חנף ישחת רעהו ובדעת צדיקים יחלצו | 9 |
Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.
בטוב צדיקים תעלץ קריה ובאבד רשעים רנה | 10 |
Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀; nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.
בברכת ישרים תרום קרת ובפי רשעים תהרס | 11 |
Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.
בז-לרעהו חסר-לב ואיש תבונות יחריש | 12 |
Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
הולך רכיל מגלה-סוד ונאמן-רוח מכסה דבר | 13 |
Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.
באין תחבלות יפל-עם ותשועה ברב יועץ | 14 |
Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
רע-ירוע כי-ערב זר ושנא תקעים בוטח | 15 |
Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.
אשת-חן תתמך כבוד ועריצים יתמכו-עשר | 16 |
Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
גמל נפשו איש חסד ועכר שארו אכזרי | 17 |
Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
רשע--עשה פעלת-שקר וזרע צדקה שכר אמת | 18 |
Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
כן-צדקה לחיים ומרדף רעה למותו | 19 |
Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.
תועבת יהוה עקשי-לב ורצונו תמימי דרך | 20 |
Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.
יד ליד לא-ינקה רע וזרע צדיקים נמלט | 21 |
Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.
נזם זהב באף חזיר-- אשה יפה וסרת טעם | 22 |
Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.
תאות צדיקים אך-טוב תקות רשעים עברה | 23 |
Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.
יש מפזר ונוסף עוד וחשך מישר אך-למחסור | 24 |
Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.
נפש-ברכה תדשן ומרוה גם-הוא יורא | 25 |
Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.
מנע בר יקבהו לאום וברכה לראש משביר | 26 |
Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.
שחר טוב יבקש רצון ודרש רעה תבואנו | 27 |
Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.
בוטח בעשרו הוא יפול וכעלה צדיקים יפרחו | 28 |
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.
עכר ביתו ינחל-רוח ועבד אויל לחכם-לב | 29 |
Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.
פרי-צדיק עץ חיים ולקח נפשות חכם | 30 |
Èso òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
הן צדיק בארץ ישלם אף כי-רשע וחוטא | 31 |
Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!