< איוב 8 >
Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé,
עד-אן תמלל-אלה ורוח כביר אמרי-פיך | 2 |
“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
האל יעות משפט ואם-שדי יעות-צדק | 3 |
Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
אם-בניך חטאו-לו וישלחם ביד-פשעם | 4 |
Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
אם-אתה תשחר אל-אל ואל-שדי תתחנן | 5 |
Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
אם-זך וישר אתה כי-עתה יעיר עליך ושלם נות צדקך | 6 |
Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
והיה ראשיתך מצער ואחריתך ישגה מאד | 7 |
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
כי-שאל-נא לדר רישון וכונן לחקר אבותם | 8 |
“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
כי-תמול אנחנו ולא נדע כי צל ימינו עלי-ארץ | 9 |
Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
הלא-הם יורוך יאמרו לך ומלבם יוצאו מלים | 10 |
Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
היגאה-גמא בלא בצה ישגה-אחו בלי-מים | 11 |
Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
עדנו באבו לא יקטף ולפני כל-חציר ייבש | 12 |
Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.
כן--ארחות כל-שכחי אל ותקות חנף תאבד | 13 |
Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
אשר-יקוט כסלו ובית עכביש מבטחו | 14 |
Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
ישען על-ביתו ולא יעמד יחזיק בו ולא יקום | 15 |
Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
רטב הוא לפני-שמש ועל גנתו ינקתו תצא | 16 |
Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
על-גל שרשיו יסבכו בית אבנים יחזה | 17 |
Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
אם-יבלענו ממקמו וכחש בו לא ראיתיך | 18 |
Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
הן-הוא משוש דרכו ומעפר אחר יצמחו | 19 |
Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.
הן-אל לא ימאס-תם ולא-יחזיק ביד-מרעים | 20 |
“Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
עד-ימלה שחוק פיך ושפתיך תרועה | 21 |
títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
שנאיך ילבשו-בשת ואהל רשעים איננו | 22 |
ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”