< איוב 25 >

ויען בלדד השחי ויאמר 1
Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,
המשל ופחד עמו עשה שלום במרומיו 2
“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
היש מספר לגדודיו ועל-מי לא-יקום אורהו 3
Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
ומה-יצדק אנוש עם-אל ומה-יזכה ילוד אשה 4
Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
הן עד-ירח ולא יאהיל וכוכבים לא-זכו בעיניו 5
Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
אף כי-אנוש רמה ובן-אדם תולעה 6
kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

< איוב 25 >