< איוב 22 >

ויען אליפז התמני ויאמר 1
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,
הלאל יסכן-גבר-- כי-יסכן עלימו משכיל 2
“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run? Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?
החפץ לשדי כי תצדק ואם-בצע כי-תתם דרכיך 3
Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ? Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?
המיראתך יכיחך יבוא עמך במשפט 4
“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?
הלא רעתך רבה ואין-קץ לעונתיך 5
Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?
כי-תחבל אחיך חנם ובגדי ערומים תפשיט 6
Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.
לא-מים עיף תשקה ומרעב תמנע-לחם 7
Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.
ואיש זרוע לו הארץ ונשוא פנים ישב בה 8
Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.
אלמנות שלחת ריקם וזרעות יתמים ידכא 9
Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo, apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.
על-כן סביבותיך פחים ויבהלך פחד פתאם 10
Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu.
או-חשך לא-תראה ושפעת-מים תכסך 11
Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran. Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
הלא-אלוה גבה שמים וראה ראש כוכבים כי-רמו 12
“Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run? Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!
ואמרת מה-ידע אל הבעד ערפל ישפוט 13
Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀? Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?
עבים סתר-לו ולא יראה וחוג שמים יתהלך 14
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.
הארח עולם תשמור-- אשר דרכו מתי-און 15
Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn ènìyàn búburú tí rìn?
אשר-קמטו ולא-עת נהר יוצק יסודם 16
A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn, ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn.
האמרים לאל סור ממנו ומה-יפעל שדי למו 17
Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’
והוא מלא בתיהם טוב ועצת רשעים רחקה מני 18
Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn! Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!
יראו צדיקים וישמחו ונקי ילעג-למו 19
Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,
אם-לא נכחד קימנו ויתרם אכלה אש 20
‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run.’
הסכן-נא עמו ושלם בהם תבואתך טובה 21
“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
קח-נא מפיו תורה ושים אמריו בלבבך 22
Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
אם-תשוב עד-שדי תבנה תרחיק עולה מאהלך 23
Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró. Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
ושית-על-עפר בצר ובצור נחלים אופיר 24
tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀, lórí erùpẹ̀ àti wúrà Ofiri lábẹ́ òkúta odò,
והיה שדי בצריך וכסף תועפות לך 25
nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
כי-אז על-שדי תתענג ותשא אל-אלוה פניך 26
Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
תעתיר אליו וישמעך ונדריך תשלם 27
Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
ותגזר-אמר ויקם לך ועל-דרכיך נגה אור 28
Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
כי-השפילו ותאמר גוה ושח עינים יושע 29
Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀, nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’ Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
ימלט אי-נקי ונמלט בבר כפיך 30
Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là, a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

< איוב 22 >